PDP: Kashamu ti gba ìwé nílé ẹjọ́ láti gbé àwọn asaájú wa

Oríṣun àwòrán, @Sen_Kashamu
Wahala to n waye laarin ẹgbẹ oselu PDP ati sẹnatọ kan lati ipinlẹ Ogun, Buruji Kashamu, ko tii jẹ rodo, lọ ree mu omi o, lẹyin ti awọn alasẹ ẹgbẹ PDP le Kashamu kuro ninu ẹgbẹ wọn.
Idi ni pe awọn asaaju ẹgbẹ oselu PDP ti fi igbe bọnu lana pe ijọba apapọ ati Kashamu ti n dete lati fi iwe asẹ ile ẹjọ gbe awọn asaaju ẹgbẹ oselu naa.
Akọwe ipolongo fẹgbẹ oselu PDP, Kọla Ọlọgbọndiyan lo fi ikede naa sita lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nilu Abuja, pẹlu afikun pe Kashamu n gbe igbesẹ naa nitori igbesẹ ti PDP gbe lati juwe ọna ile fun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọ́lọgbọndiyan ni "Awa la ni ẹgbẹ wa, ti wọn si yan wa lati maa se akoso rẹ nibamu pẹlu ofin orilẹ-ede Naijiria. Bi a si se n tukọ ẹgbẹ oselu PDP wa nibamu pẹlu ofin naa, to fi mọ awọn igbesẹ taa n gbe ati ipinnu ti a n se. Nitori naa, gbogbo igbesẹ kigbesẹ ti ẹnikẹni ba gbe lati ba ẹgbẹ naa laa tako pata-pata."

Oríṣun àwòrán, @PDP
Ọlọgbọndiyan, ẹni to se apejuwe igbesẹ bi ijọba apapọ lati dena de Saraki ati Ekweremadu, ti wọn jẹ asaaju ile asofin apapọ, bii iwa ọyaju ati idunkoko mọni lati ọdọ ijọba ẹgbẹ oselu APC ati aarẹ Muhammadu Buhari.
O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP lati mase foya nitori iwa idunkoko mọni naa, to si tun n rọ awọn ololufẹ eto iselu ijọba tiwa n tiwa kaakiri agbaye lati dide tako iru iwa aidaa yii.









