CBN pàṣẹ kí MTN àti àwọn ilé ìfowópamọ́ da $8bn pada

Ami idanimọ Banki apapọ orilẹede Naijiria

Oríṣun àwòrán, Central Bank of Nigeria

Àkọlé àwòrán, Banki apapọ orilẹede Naijiria lo n se isakoso eto ọrọ owo Naijiria
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ile ifowopamọ apapọ l'orileede Naijiria (CBN) ti paṣẹ ki awọn ile ifowopamo mẹrin kan san owo itanra to le ni biliọnu marun naira.

Standard Chartered Bank, Stanbic-IBTC, Citibank, ati Diamond Bank wa lara awọn banki ti CBN lo padi apopọ pẹlu ile isẹ MTN lati tapa sofin idunadura to de pasiparọ owo lorileede Naijiria.

Bakannaa ni CBN ni ki wọn da owo to to biliọnu mẹjọ dọla pada si akoto ijọba fun pe MTN n fi ọna eru da owo pada si orileede South Africa.

Ile ifowopamọsi agba naa fi ikede naa sita loju opo Twitter re lojo aje.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ikede naa se atupalẹ owo itanran ti awọn Banki naa yoo san bayi pe:

  • Standard Chartered yoo san N2.4bn
  • Stanbic IBTC N1.8bn
  • Citibank N1.2bn
  • Nigba ti Diamond Bank yoo san owo itanran N0.25bn