Ekiti2018: Ilé ẹjọ́ ni Fayoṣe kò láṣẹ láti f'òfin de Fayẹmi láti dupò òṣèlú

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government
Ile ẹjọ giga kan nilu nilu Abuja ti wọgile abajade igbimọ iwadi kan ti ipinlẹ Ekiti gbe kalẹ, eleyi to fi ofin de gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi pe ko lẹtọ lati di ipo ilu mu mọ nipinlẹ naa.
Ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party, APP lo pe Kayọde Fayẹmi lẹjọ pe ko lẹtọ lati dije nibi idibo sipo gomina ipìnlẹ Ekiti ti yoo waye loṣu yii, nitori iwe aṣẹ ti ijọba ipinlẹ Ekiti gbe jade pe Fayẹmi ko lẹtọ l'abẹ ofin lati di ipo iṣejọba kankan mu nipinlẹ naa.
Ninu idajọ to gbe kalẹ ni ọjọ Iṣẹgun, Onidajọ O.A. Musa ni ipẹjọ ẹgbẹ oṣelu APP ko lẹsẹ nlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Onidajọ Musa ṣalaye pe Fayẹmi lẹtọ lati dije lasiko ibo gomina ipinlẹ Ekiti to n bọ lọna, nitori idajọ ile ẹjọ to ga julọ l'orilẹede Naijiria lori awọn ẹjọ to jọ iru eyi latẹyin wa ni pe, idajọ igbimọ oluwadi ko lee da ọmọ orilẹede Naijiria kankan duro lati maa lee dije fun idibo.
Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, oludari ẹka iroyin nileeṣẹ ipolongo Kayọde Fayẹmi, Ọgbẹni Wọle Olujọbi ni idajọ naa kii ṣe kayefi fun awọn nitori awọn gbagbọ pe gbogbo igbesẹ ti ijọba Gomina Ayọ Fayoṣe gbe lori igbimọ iwadi naa lo ni ọwọ oṣelu ninu, ti ko si fara mọ eto idajọ ododo.
Akitiyan lati kan si igun ijọba ipinlẹ Ekiti lori ọrọ naa ko so eso.













