'Ọpọ̀ ẹ̀mí èèyàn ló bọ́ lọ́wọ́ Abacha láàrín 1993 sí 1998'
Ìgbà lonígbà ń kà, Ẹkọ́ ni ikú Abacha jẹ́ fún Nàìjíríà
Bí ọmọ kò bá ba ìtàn, o di dandan kó ba àrọ́bá to jẹ baba ìtàn.
Orilẹ-ede Naijiria ṣeto idibo to yaranti ni ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 1993 eyi ti Ọgagun Ibrahim Babangida to n tukọ Naijiria nigba naa wọgile.
Babangida gbe ijọba kalẹ fun Oloye Ernest Ṣonẹkan labẹ ijọba fìdíhẹẹ́ ni èyi ti Ọgagun Sani Abacha gba ijọba lọwọ rẹ̀ lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kọkanla, ọdun 1993.
Èrò àwọn ènìyàn lórí Abacha lẹyin ogun ọdun to ti kú
Awọn kan gboriyin fun un nipa eto ọrọ aje ṣugbọn ọpọ eeyan lo bẹnu atẹ lu Abacha pé iṣẹ ọwọ rẹ buru jai nigba aye rẹ.
Yoruba ni: ìgbẹ̀yìn lójù nitori pe ohun gbogbo tóo ba ṣe loni, ọrọ itan ni lọla.
