Fídíò BBC yọ àwọn èèyàn FIFA níṣẹ́ ṣááju Russia 2018
Ó lé ni ọgọ́rùn ún òṣìṣẹ́ eré bọọlu tó kó sí páńpẹ́ ìwádìí náà
Anas tí ó jẹ́ akọ̀ròyin ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ tó máa ń da agọ̀ bojú kí wọn má baà lé rí ojú rẹ̀, sọ pé, màgòmágó àti rìba ti ba ere bọ́ọ̀lù jẹ́ ní Ghana.
Lẹ́yin ìwádìí iléesẹ́ BBC pẹ̀lú àjọṣepọ̀ Anas Arameyaw Anas, akọ̀ròyìn ọmọ Ghana kan, nijọba Ghana ṣe ìkéde tuntun.
Èyí tó ga jù nibẹ ni ti ọ̀gá agba àjọ tí ó ń rí sí eré bọ́ọ̀lù ni Ghana (GFA), Kwesi Nyantakyi, tí ó gba ẹgbẹ̀rún lọ́nà márunléọgọ́ta dọ́là gẹ́gẹ́ bíi rìbá.
Bayii, iwadii yii ti n bi ìgè ati àdùbí
- Ijọba orile-ede Ghana ati awọn ile igbimọ aṣofin bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.
- Bakan naa ni wọn f'ofin de gbogbo ifésẹwọnsẹ Ghana to yẹ ko waye, eyi tumọ si pe, yoo pa idije Liigi Abẹ́lé àti t'àwọn agbbọọlu agba lára.
- Ajọ agbabọọlu lagbaye, FIFA ti ni ki Nyantakyi to jé ọmọ igbimọ FIFA lọ rọọkun sile fun aadọrun ọjọ.
- Aare ajọ agbabọọlu Ghana (GFA), Nyantakyi Kwasi ti kọwe fipo rẹ silẹ.
- Rẹfiiri ọmọ ilẹ Kenya, Marwa, to yẹ ko ṣiṣẹ ni Russia 2018 naa ti kọwe fipo rẹ silẹ.
- Iwadii yii fi aṣemaṣe lasiko idije WAFU 2017 han, o tun fi Jallow, oludari ere bọọlu lati Gambia naa han ninu fiimu ọhun pe o gba riba.
Ìrètí àwọn ènìyàn lórí Russia 2018
- Àwọn ololufẹ ere bọọlu gba pe iwadii yii ti n bi eso rere to yẹ fun àfọ̀mọ́ awọn oṣiṣe ere bọọlu lagbaye.
- Wọn gba pe abajade iwadii Anas ati BBC yoo ṣe atunṣe to yẹ si FIFA lagbaye ati ni ajọ ere bọọlu orile-ede kọọkan.
- Ati pe, eyi yoo jẹ ẹkọ fun gbogbo oṣiṣẹ ere bọọlu lagbaye
- Ajọ FIFA ti tẹpẹlẹ mọọ pe o lodi si ìṣe wọn lati gba ẹ̀bùn lọwọ ẹnikẹni.
