Zuma: Èmi kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́

Jacob Zuma

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jacob Zuma ń jẹ́jọ́ lórí ẹ̀sùn ìwà ìbàjẹ́

Ọgọọrọ awọn alatilẹyin lo peju si ile ejọ giga nilu Durban l'orilẹ-ede South Africa, nibi ti Aarẹ tẹlẹ ri Jacob Zuma ti farahan lori ẹsun iwa ibajẹ

Ọgbẹni Zuma n jẹjọ lori ẹsun iwa ibajẹ onikoko mẹrindinlogun, ẹsun iwa ajẹbanu ati ṣiṣe owo ilu bii bílíọ́nù méjì àti ààbọ̀ dọ́là ($2.5 bn), ti wọn fẹ fi ra ohun ija oloro, kumọkumọ.

Ifarahan Zuma ni ile-ẹjọ l'ọjọ Ẹti, lo tumọ si pe igbẹjọ naa n tẹsiwaju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu ọrọ rẹ, Aarẹ ana, Zuma, to ba awọn alatilẹyin rẹ sọrọ ni ede Zulu, sọ pe, oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan òun.

Ọpọ abẹnugan ninu ẹgbẹ oṣelu ANC, ni wọn duro ti Zuma nibi to ti n bawọn eniyan sọrọ.

Atilẹyin ti awọn kan fun Zuma lati inu ẹgbẹ naa, lo ti jẹ ki ahesọ ọrọ wa pe, ko si isọkan ninu ẹgbẹ naa saaju idibo gbogbo-gboo to n bọ.

Sugbọn Zuma ni, ko si otitọ ninu ọrọ naa.