Ọmọ orílẹ́èdè Gẹ̀ẹ́sì méjì sọnù nínú ọgbà ẹranko

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọfiisi to n ri si ọrọ ilẹ-okeere ti kàn si awọn ẹbí wọn ati awọn alaṣẹ ijọba
Iṣẹlẹ naa waye lapa ariwa ilu Goma ni ila-oorun orilẹ-ede D.R. Congo ninu ọgba ẹranko ti Virunga National Park.
Akọroyin fun BBC, Louise Dewast, t'owa ni olu-ilu orilẹ-ede naa, ni Kinshasa ni awọn to d'ira pẹlu ohun ija olóró maa n ṣọṣẹ l'agbegbe naa.
Ṣugbọn o fi kun ọrọ pe awọn ọmọ ogun orilẹ-ede D.R Congo ma n wa nibẹ nigba gbogbo lati gbogun ti wọn.
Ọpọlọpọ eeyan pẹlu awọn obinrin ati ọmọde ni wọn ti ji gbe ni agbegbe naa lati ọdun 2016.









