Ethiopia: Abiy Ahmed ni olóòtú ìjọba tuntun

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ti bura sipo fun Abiy Ahmed gẹgẹ bi olóòtú ìjọba orilẹẹde Ethiopia.
Ahmed ni yoo rọpo Hailemariam Desalegn, to kọwe fipo silẹ losu to kọja.
Ibura sipo rẹ la gbọ wi pe o n waye ni ile igbimọ asofin nibi ti yoo ti ba awọn asofin sọrọ.
Ko ti daju boya yoo salaye ojupọnna ti ijọba re yoo tọ nibi ayẹyẹ naa.








