You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Champions League: Ronaldo tàn bí oòrùn níwájú Juventus
Góòlù àkẹ̀yìn sílé gbá tí gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù ikọ̀ Real Madrid, Christiano Ronaldo gbá wọlé ni ariwo rẹ̀ gbòde níbi ìwọnsẹ̀ tó wáyé láàrín Juventus àti Real madrid nínú ìdíje Champions league tó wáyé lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.
Góòlù àwò dàmi ẹnu yíí kún ara góòlù méjì tí Ronaldo gbá wọlé nínú mẹ́ta tí Real Madrid fi ṣe àgbà Juventus. ìṣẹ́jú kẹta ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà ni Ronaldo ti kọ́kọ́ mi àwọ̀n kí ó tó di wí pé ó tún fò sókè fi ẹ̀yìn gbá bọ́ọ̀lu wọ inú àwọn Juventus.
Ńṣe làwọn olólùfẹ́ Juventus dìde sókè rọ òjò àtẹ́wọ́ lu Ronaldo lẹ́yìn tó gbá góòlù náà wọlé.
Gbogbo bí Juventus ṣe gbìyànjú láti yíí ojú ọ̀rọ̀ padà ló já sí pàbó tí aláàkóso ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà sì tún lé atamátàsé ikọ náà, Paulo Dybala jáde.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ní ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ míràn tó wáyé, Bayern Munich lu Sevilla mọ́lé pẹ̀lú àmì ayò méjì sí ẹyọ kan.
Agbábọ́ọ̀lù Sevilla, Jesus Navas ló kọ́kọ́ gbáá bọ́ọ̀lù wọ ilé ara rẹ̀ kí Thiago Alcantara tó fi orí gbé òmíràn wọlé.
Ṣáájú méjí yíí ni Pablo Sarabia, ti gbé Sevilla síwájú kí omi tó tẹ̀yìn wọ ìgbín wọn lẹ́nu.