Ife Ẹyẹ Agbaye ti Russia 2018 balẹ bagẹ si BBC

Lara awọn aworan nibi isafihan Ife Ẹyẹ agbaye ti Russia 2018 ni Ile-isẹ BBC.

Wọn fi asọ bo ife ẹyẹ agbaye
Àkọlé àwòrán, Ni ọdun 1930 ni idije ife ẹyẹ agbaye kọkọ waye
Wọn n sisọ loju ife ẹyẹ agbaye
Àkọlé àwòrán, Orilẹede Uruguay lo kọkọ gbalejo idije yii ni ọdun 1930
Ife ẹyẹ agbaye duro ninu apoti diigi ti wọn gbe e si
Àkọlé àwòrán, Orilẹede Egypt ni orilẹede Afirika to kọkọ kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye
Ọga agba fun eto iroyin ni ileeṣẹ BBC lorilẹede Naijiria, Peter Okwoche pẹlu gbajugbaja agbabọọlu orilẹede France ni, Chritian Karembeu pẹlu Ọgbẹni Peter Njonjo to jẹ aarẹ ileeṣẹ Coca cola lẹkun iwọ oorun ilẹ Afirika duro pẹlu ife ẹyẹ agbaye
Àkọlé àwòrán, Ọdun 1994 ni orilẹede Naijiria kọkọ kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye
Awọn oniroyin duro pẹlu irinsẹ iyaworan ati igbohunsilẹ wọn
Àkọlé àwòrán, Saaju idije ti yoo waye ni orilẹede Russia lọdun 2018, igba marun ọtọọtọ ni orilẹed4e Naijiria ti lọ si idije ife ẹyẹ agbaye
Awọn osisẹ BBC ati awọn ololufẹ bọọlu ti wọn wa wo ife ẹyẹ agbaye ni ọfiisi BBC
Àkọlé àwòrán, Naijiria ko kọja ipele keji idije yii ri lati ọdunmẹrinlelogun ti o ti n lọ si idije yii
Fẹmi Ọpabunmi ni agbabọọlu to kere julọ lati orilẹede Naijiria ti yoo kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye
Àkọlé àwòrán, Fẹmi Ọpabunmi ni agbabọọlu to kere julọ lati orilẹede Naijiria ti yoo kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye
Timi Dakolo duro niwaju ife ẹyẹ agbaye
Àkọlé àwòrán, Orilẹede Brazil lo tii gba ife ẹyẹ agbaye ju lọ ni igba marun ni wọn si ti gba a
Arabinrin kan to wa lara awọn ololufẹ bọọlu to wa wo ife ẹyẹ agbaye n ya fọto pẹlu ife ẹyẹ naa
Àkọlé àwòrán, Orilẹede meji ni ilẹ Afirika lo tii bọ si ipele ko mẹsẹ o yọ quarter finals, awọn si ni Cameroun ati Ghana
Arakunrin kan to wa lara awọn ololufẹ bọọlu to wa wo ife ẹyẹ agbaye n ya fọto pẹlu ife ẹyẹ naa
Àkọlé àwòrán, Orilẹede mejilelọgbọn ni yoo kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti ọdun 2018

Awọn aworan yii wa lati ọwọ Ile-ise iroyin BBC.