Lauretta Onochie: Àwọn ará ìlú lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ̀ òfin láti fi ẹjọ́ ẹni tó ń náwó yàlàyòlò sun agbófinró

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agbẹjọro kan, Jiti Ogunye, ti sọ pe ko buru ki eeyan maa na owo yalayala labẹ ofin, ṣugbọn ijọba le ṣe iwadii owo naa ti wọn ba fi ẹjọ irufẹ ẹni bẹẹ sun pe idi owo rẹ ko mọ.

Nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ, Ogunye sọ pe awọn agbofinro kii ṣe arinurode olumọran ọkan ti yoo mọ ẹni to n ṣe jibiti lai si iranlọwọ awọn ara ilu.

Gẹgẹ bo ṣe, "ofin ko sọ pe ki eeyan má na owo tí kò pa, ohun ti ofin sọ ni pe ki eeyan ma fi ọna ẹru pa owo tabi ko jokoo sibi kan lati ma na owo to ji.

O ṣalaye pe "ti eeyan ba n na owo yala-yolo, ti awọn agbofinro si ṣe iwadii, ti wọn si ka ẹṣẹ mọ irufẹ ẹni bẹẹ lọwọ, nigba yẹn ni ẹni naa da ẹṣẹ labẹ ofin."

"Ṣugbọn a ko le sọ pe eeyan ti ṣẹ si ofin nitori o n nawo yala."

Ṣaaju ni amugbalẹgbẹ Aarẹ Muhammadu Buhari, Lauretta Onochie ti kọkọ sọ loju opo Twitter rẹ pe gbogbo awọn to n gbe igbe aye ti apo iṣuna wọn ko ka le kawọn pọn ro ẹjọ niwaju adajọ.

Lauretta ni "O ti pẹ ti mo ti n reti ki Naijiria ni iru ofin yii to wa nilẹ Gẹẹsi, eyii to faye gba awọn eeyan lati fi ẹjọ ẹni to n na inakuna, ti ko si ni ọna kan pato ti owo ti n wọle, sun ijọba.

Amubalẹgbẹ Aarẹ ọhun sọ pe inu oun dun pe ajọ to n ṣewadii iwa jẹgudujẹra, ICPC, ti ba ọrọ naa de ile to ga julọ ni Naijiria.

Nigba ti agbẹjọro Ogunye n fesi si ọrọ Lauretta, o ni kii ṣe ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lo n ṣe ofin, bi ko ṣe awọn ile igbimọ aṣofin ijọba apapọ, ati ti ijọba ipinlẹ.

O pari ọrọ rẹ pe, ko tii si ofin kankan ni Naijiria to sọ pe ara ilu ko le na owo bo ṣe wuu labẹ ofin.

"Ṣugbọn ara ilu lẹtọọ labẹ ofin lati fi ẹjọ irufẹ ẹni bẹẹ sun awọn agbofinro, bo ti tilẹ jẹ pe inakuna kii ṣe ẹṣẹ labẹ ofin."