Side effects of birth control: Wo ipa tí òògùn ìfètò sọ́mọ́ bíbí le ní lára rẹ

Ṣé o fẹ́ lo òògùn ìfètò sọ́mọ́ bíbí?

Wo ipa tó le ní lára rẹ kí o tó lò ó

Bi ẹgbẹẹgbẹ̀rún obinrin ni agbaye ṣe n lo oogun oyinbo lati feto si ọmọ bibi, naa ni Vanessa , obìnrin kan to n gbe ni ilu Boston, lorilẹ-ede America naa se n lo.

Sugbọn abajade rẹ fun Vanessa yatọ si ti si ti awọn obinrin to ku.

O ti ẹ sọ pe abajade oogun naa lara oun ti yi igbeaye oun pada titi aye.

Kini o ṣẹlẹ si Vanessa?

Vanessa salaye pe: 'Mo ro pe mo ni aisan ẹjẹ rírú ni'

Ile ni mo wa lọjọ naa, ti mo fẹ ẹ gun oke, ni mo sakiyesi pe o nira fun mi lati mi.

"Iru nkan bẹ ẹ ko ṣẹlẹ si mi ri."

Vanessa kuku lọ si ibi isẹ rẹ lọjọ naa, lai fi ilera rẹ ṣe.

Àmọ́ o ya si ileewosan naa.

Kini Vanessa ba bọ nile iwosan to lọ?

Vanessa ni: "Wọn fun mi ni nkan ti yoo si ibi ti èémí n gba wọle-jade ni ara mi.

" Ara tu mi diẹ, mo si bẹrẹ si ni i mi.

"Wọn ni kí n lọ ya fọto ẹ̀dọ̀fòòró mi, nibẹ ni wọn ti sọ fun mi pe wọn ri òjìji kan."

Ojiji bi i ti bawo?

Ni ọjọ keji, wọn sọ fun Vanessa pe ko ni aisan ẹjẹ rírú, sugbọn yoo se ayẹwo míì.

Bawo ni irinajo Vanessa ṣe lọ nile iwosan?

O to oṣu kan ko to o ni anfaani lati ri dokita.

Nigba ti yoo si fi ri i, bo ṣe n mi ti buru ju ti tẹlẹ lọ.

Vanessa ni: "Ile ni mo wa lọjọ naa ti mo n fọ aṣọ. Mo fẹ ẹ lọ mu nkan ni oke, ni èémí mi tun salọ.

Vanessa ni: "Kia ni mo ṣi bọtinni aṣọ ti mo wọ, ki n to ṣubú si ilẹ ile ìdáná nitori pe mi o le mí mọ.

"Nise ni gbogbo ara mi dabi i pe o ti poora.

Ikùn, aya, ati apá bẹrẹ si ni i ro mi. Mo ro pe ma a mi ẹ̀jẹ̀ rírú ni."

Vanessa ko lọ sileewosan, sugbọn o pe dokita rẹ lori foonu. Oun lo si gba a nimọran pe ko tete lọ sileewosan ni kiakia.

Ayẹwo ti wọn ṣe fun lo fihan pe ẹ̀jẹ̀ ti di si àyà rẹ ni. Ohun lo si di ọna ti eemi n gba.

Dokita sọ fun un pe o ṣe e ṣe ko jẹ oogun ifetosọmọ bibi to n lo lo fa a.

Awọn anfaani oogun ifetosọmọ bibi:

Ti o ba lo deedee:

  • Oogun ifetosọmọbibi a maa n dena oyun ni ọna ìdá mọkandinlọgọrun.
  • Ko ni idiwọ fun ibalopọ
  • O ṣaba ma n mu ki nkan oṣu rẹ wa deede, ko kere, lai mu inira lọwọ
  • O le din irora ku saaju ki nkan oṣu to o bẹrẹ
  • O le din ewu oyun iju, ati aarun ti kii se jẹjẹrẹ inu ọmú ku
  • O le din kokoro ara ku

Kii ṣe gbogbo eeyan ni ẹ̀jẹ̀ maa n di si ni àyà ṣugbọn alaye ree lori bi o ṣe le ṣẹlẹ:

Iṣẹ ti eroja estrogen ati progesterone to wa ninu awọn oogun ifetosọmọ bibi ma n se ni pe o ma n da ẹyin obìnrin dúró 'ovulation' ati oyun.

Ni ṣe ni yoo mu ki omi to wa ni ẹnu ọna ile ọmọ obìnrin ko ki debi i pe àtọ̀ ọkùnrin ko ni le raaye kọja sinu ile ọmọ.

Gẹgẹ bi dokita onimọ nipa ẹ̀yà ara obinrin kan ṣe sọ lorilẹ-ede South Africa, Dokita Nene Zozo ṣe sọ, abajade ti awọn oogun naa ma n ni ni ara ni èébì, ara sísan, inu wiwu ati kokoro ara.

O ni, ori fifọ, ìrora ninu ọmú, tabi ki wọn o ma le jẹun daadaa ni abajade ti awọn obinrin mii ma n ni.

Dokita Nene ṣalaye pe awọn eroja to maa n pese ẹ̀jẹ̀ wa ninu ara, sugbọn ti wọn ba ti ko firi kokoro aifojuri, o se e ṣe ki ẹ̀jẹ̀ o ma a di ninu ara.

Yatọ si awọn abajade yii, ajọ to n mojuto eto ilera lorilẹ-ede United Kingdom, NHS, sọ lori ayelujara rẹ pe oogun ifetosọmọ bibi tun le fa Ẹ̀jẹ̀ riru.

Ki obinrin ma a ri ẹ̀jẹ̀ kekeeke ni oju ara rẹ fun oṣu diẹ lẹyin to ba bẹrẹ si ni i lo oogun naa.

Bakan naa ni ayẹwo fihan pe o lọwọ ninu bi awọn obinrin kan ṣe ni jẹjẹrẹ ọmú ati bi ẹ̀jẹ̀ ṣe n di ninu ara wọn.

Awọn kan wà ninu oogun naa to le fa aisan rọpa-rọsẹ.

Sugbọn ṣa, anfaani wa lati tete parọ ilana ifetosọmọ bibi naa ti ko ba ọ lara mu. Sugbọn rii daju pe o ba dokita sọrọ nipa akiyesi rẹ.