You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Reincarnation: Ṣé lọ́ọ̀tọ̀ ní àkúdááyà wà? ẹ̀ wo ìrírí àwọn tó rí ènìyàn wọn tó kú láàyè
Arameri ni iṣẹlẹ yii nigba ti ori ayelujara mi titi pẹlu ẹnikan to ni oun ri ara ile oun ti wọn fẹ lọ sin lẹyin to ti ku, ni oju titi nibi ti o ti fẹ wọ ọkọ.
Iroyin naa fi aworan ọmọkunrin kan han ti wọn ri ni opopona Douala ni Cameroon lẹyin ti ọmọ naa ti ku lẹyin to mu ọti to ni majele.
Ileeṣẹ iroyin naa ni ọmọkunrin naa ti orukọ rẹ n jẹ ''Junior Njenkal'' ni wọn ni o ku lẹyin to jẹ majele, lasiko to mu ọpọlọpọ ọti lile.
Lẹyin naa ni awọn ẹbi rẹ mura lati gbe lọ si ile igbokusi lẹyin to papoda, amọ ni ọjọ isinku rẹ ni arale awọn ẹbi rẹ ni wọn ya awọran rẹ pẹlu fidio nibi to ti duro si ẹgbẹ titi to fẹ gun ọkada.
Mọlẹbi naa ko gba ohun ti oju rẹ ri gbọ, lo ba mu ẹrọ ilewọ rẹ jade to si ya aworan rẹ.
Lẹyin to duro fun igba diẹ, ni ọmọkunrin naa bọ si ori ọkada pẹlu eniyan meji, to si lọ.
Ki eleyii to waye ni wọn ni iya rẹ lọ si ile igbokusi lati lọ gbe oku rẹ amọ ti wọn sọ fun wi pe baba rẹ agba ati ibatan rẹ ti wa gbe oku rẹ lati lọ sin.
Lẹyin eyi, ni araale naa wa sọ fun awọn obi rẹ ni itẹ ti wọn ti fẹ sin oku rẹ, ti wọn si gbe ara rẹ si inu ilẹ rẹ.
Ọpọlọpọ awọn ọmọ eniyan lo ti n fesi si iṣẹlẹ naa lori ayelujara, bi awọn miran ṣe n sọwipe ko ṣeeṣe, ni awọn miran n sọ wi pe iru iṣẹlẹ yii wọpọ ni ilẹ Afrika.
Awọn miran ni awọn ko gbagbọ ninu iru iṣẹlẹ naa, ati wi pe itan abalaye ni.
Amọ, awọn miran ni iru iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ si mọlẹbi tabi ibatan wọn ti o ti la iru iṣẹlẹ yii kọja.