Amad Diallo: Manchester United ra Ahmad Diallo lọ́wọ́ Atalanta fun ọ̀dun mẹ̀rin abọ̀

Oríṣun àwòrán, Twitter/Ahmad Diallo
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti fi ẹnu adehun jona lori rira Amad Diallo, agbabọọlu Atalanta bayii.
Ni bi a ṣe n sọrọ yii ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti kede rẹ faye gbọ pe Diallo ti gunlẹ si gbagede Old Trafford lati ikọ Atalanta lorilẹede Italy .
Ole Gunnar Solskjaer, akọnimọọgba Manchester United ni oinu oun dun pe adehun idunadura naa bọ si nitori pe: "Ni igbagbọ oun, Diallo wa lara awọn ọdọ agbabọọlu taye n wari fun lọwọ lagbaye."
Ọdun mẹrin abọ ni adehun naa ti wọn ṣe pẹlu agbabọọlu ọmọ orilẹede Cotedivoire naa.
Ninu ọrọ tirẹ, Ahmad Diallo ni ọdun to kọja loun ti n reti ki adehun naa bọsi nitori o da oun loju pe ẹgbẹ agbabọọẹu to ṣe rẹgi fun idagbasoke oun ni Manchester United jẹ.








