Coronavirus in Nigeria: Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé ìtọ̀ àti imí màálù le wo ààrùn coronavirus?

Àkọlé fídíò, Ṣé lóòtọ́ọ́ ni pé ìtọ̀ àti imí màálù le wo ààrùn coronavirus?

Oriṣiiriṣii nnkan lawọn eeyan n sọ pe o le wo aarun coronavirus ti o ba gbogbo aye finra lọwọ.

Ọkan lara wọn ni itọ ati igbẹ maalu. Ṣugbọn ohun ti a mọ ni pe itọ tabi igbẹ maalu ko le ṣ'oogun aarun covid-19.

Gẹgẹ bi ọrọ ti ajọ to n ri si eto ilera lagbaye, WHO ṣe sọ, itọ ati igbẹ maalu ko le sọ bo ya eeyan ni aarun coronavirus.

Ẹ wo alaye lẹkunrẹrẹ ninu fidio yii.