Kogi: Ilé aṣòfin ti bẹ́rẹ́ ìgbésẹ̀ àti rọ igbákejì gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi lóyè

igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba

Oríṣun àwòrán, dailypost

Afaimọ ki ipinlẹ Kogi maa ni igbakeji gomina miran laipẹ.

Ti iku kọ, bẹẹ ni kii ṣe ti arun, ṣugbọn o ṣee ṣe ki iji aawọ to n waye laarin igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba ati Ọga rẹ, iyẹn gomina Bello o gbe igbakeji gomina naa lọ.

Gẹgẹ bii ara apẹrẹ iji naa ni bi ile aṣofin ipinlẹ kogi ṣe bẹrẹ igbesẹ ati rọọ loye ni ọjọ iṣẹgun.

Ile aṣofin ipinlẹ naa ti ke si adajọ agba ipinlẹ naa, Onidajọ Nasir Ajanah lati gbe igbimọ ẹlẹni meje kan kalẹ lati se iwadii awọn ẹsun aṣemaṣe ti wọn fi kan igbakeji gomina naa.

Kike si adajọ agba lati gbe igbimọ oluwadi kalẹ ni igbesẹ keji ti ofin orilẹede Naijiria la kalẹ fun yiyọ awọn to ba di ipo mu bii aarẹ, igbakeji aarẹ, gomina ati igbakeji gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria.

Olori ọmọẹgbẹ oṣelu to pọ julọ nile aṣofin ipinlẹ Kogi, Abdullahi Bello-Balogun lo lewaju aba kan ti wọn gbe ka iwaju ile naa lori ẹsun pe igbakeji gomina ọhun gbiyanju ati da yẹyẹ gomina Yahaya Bello ati ijsba ipinlẹ naa sita gbangba ati pe gbangba bayii lo ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ alatako lasiko idibo aarẹ to kọja.

Mẹtadinlogun ninu aṣofin mọkandinlogun to wa ni ile naa ni wọn fi ọwọ si igbesẹ naa; ti wọn si fun adajọ agba ni gbedeke ọjọ meje lati gbe igbesẹ agbekalẹ igbimọ naa.

Laipẹ yii ni Igbakeji gomina ipinlẹ Kogi, Simon Achuba pariwo fun aye gbọ lasiko to ba awọn oniroyin sọrọ pe aarin oun ati ọga oun ko gun eyi to jẹ koko ninu gbun-gbun-gbun to ti n waye laarin awọn mejeeji lati igba diẹ sẹyin.

Ninu ọrọ to ba BBC Yoruba sọ, agbẹnusọ fun Olori ié aṣofin ipinlẹ Kogi, Ọgbẹni Fẹmi Olugbemi ni igbesẹ ti Achuba gbe lati lọ sọ ọrọ ile si ita gbangba dipo ko wa siwaju ile naa lati fi ẹjọ ọga rẹ sun, iyẹn bi ọga rẹ ba ṣẹ ẹ nitotọ lo jẹ ki wọn gbe igbesẹ naa.

Amọṣa, gomina ipinlẹ Kogi ni oun ko mọ nipa ohun ti oju igbakeji oun n ri lọwọlọwọ.

Agbẹnusọ fun un, Onogu Muhammed ni Gomina Bello ko mọ ni pa oun to waye nile aṣofin ipinlẹ naa nitori awọn n bọwọ fun eto konko jabele kaluku lo mi ṣe ti ẹ laarin awọn ẹka ijọba gbogbo nibẹ.