Kanu Nwakwo: Òní ni ọjọ́ ìbí Kanu, àwọn ǹkan tó ti gbé ṣe rèé

    • Author, Yemisi Oyedepo
    • Role, Broadcast Journalist
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Oní ni ọjọ́ ìbí Kanu Nnwankwo, gbajúgbajà agbábọ́ọ̀lù orilẹ̀èdè Nàìjíríà, Super Eagles tẹ́lẹ̀ rí.

Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ nípa ọjọ́ ìbí rẹ̀ yìí ló sì ti gbá síta lóri òpó twitter rẹ pé, òun dúpe lọ́wọ́ Ọlọrun fún ọjọ́ òní, ó fi kún un pé òun ṣetan láti túbọ tẹra mọ́ isẹ́ síì.

Ìyàwó Kanu, @amarakanu wà lára àwọn to kí Kanu lóri òpó instagram rẹ̀, ó ní Kí Ọlórun dáhùn si gbogbo èrò ọkan rẹ̀. "O kú orire ọjọ ibi ọkọ mi, olowo ori mi, baba awọn ọmọ mi, akọni lórí ilẹ̀".

Ọ̀pọ̀ àwọn àwọn ọmọ Nàìjíríà ló ti bẹ̀rẹ̀ si ni ki Kanu kú orire ọjọ́ ìbí.

Díẹ̀ lára ǹkan to yé kí o mọ̀ nípa Kanu Nnwankwo rèé

  • Kanu Nwakwo tó mílíọ̀nù mẹ́sàn-an naira ní ti gbogbo ǹkan ìní àti owó ti ìròyìn fi ye ni pé Kanu tí gbogbo ènìyàn máa ń pe ni Papilo ní ilé ni Victoria Island, Owerri, ipinle Eko, Dubai, àti London, o ni ọkọ̀ Ferrari, Mercedes Benz ati Audi, ó ni ilé iṣẹ́ mohunmaworan fún ere ìdárayá .
  • Kanu jẹ asojú UNICEF, asoju Startimes, bákan náà lo gba àmì ẹ̀yẹ OON.
  • Ní àsìkò kan Kanu ni àìsàn ọkàn, to sì jà fitafita, èyí sì ni ó ṣe okùnfà ti Kanu fi ṣe àgbékalẹ àjọ Kanu Heart Foundation lati máa ran àwọn to ba ni irú ìpèníjà yìí lọ́wọ́. O fẹ́ láti kọ ilé ìwòsàn ńla márùn-un ńlánlá sí ilẹ̀ Afirika láti mú ìdẹ̀rùn bá àwọn ti o bá ń kojú irú àìlera yìí, bákan náà ní ajọ rẹ̀ ti gbèrú síi láti maa ṣerànwọ́ fún àwọn tí kò níle.
  • Kanú ti gbà àmì ẹ̀yẹ UEFA Champions League, ife ẹ̀yẹ̀ UEFA ó gba ife ẹ̀yẹ FA ní ẹ̀mẹtàa àti ọmọ ilẹ̀ Afirika tó mọ bọọlu gbá jùlọ, ó jẹ ọkan lára àwọn agbábọọlù tó gba Premiere League, àmì ẹ̀yẹ̀ Olympic Gold Medal.
  • Yàtọ̀ sí ikọ àgbábọọlu Nàìjíríà, Kanu ti gbá bọọ̀lù fún ikọ̀ mẹ́fà, Nwuanyanwu National, Ajax, Inter Milan, Arsenal, West Bromwich Albion àti Portsmouth, ó si gbá bọ́ọ́lù mẹ́jìdínláàdọ́fa sáwọ̀n.
  • Kanu Nwankwo fẹ Amarachi lọdun 2004 nígbà tó wà ni ọmọ ọdún mẹ́jìdínlógun, ọlọrún fi ọmọ mẹ́ta ta wọ́n lọ́rẹ. Láìpẹ́ yìí ni ìyàwó Kanu pari ẹkọ́ láti gba oyè gíga nínú ìmọ̀ òfin MBA rẹ.