Nigeria Elections 2019: Tinubu ní òun kò lé Ajimobi kúrò ní APC

Oríṣun àwòrán, Newspeakonline
Olori ẹgbẹ oṣelu APC, Asiwaju Bola Tinubu ti ni irọ ni iroyin to jade pe oun ti sọ fun gomina Ipinlẹ Oyo, Abiola Ajimobi ko ma ṣe farahan nibi ipolongo ibo gomina ẹgbẹ oṣelu naa.
Atẹjade kan lati ọwọ Tunde Rahman to jẹ oludamọran Tinubu lori ọrọ iroyin ni ko si ootọ kankan ninu iroyin kan to jade wi pe Tinubu gbe igbesan naa lori bi APC ko ṣe ṣe daadaa ninu idibo sile aṣofin agba ati ti aarẹ.
Abiọla Ajimọbi nikan ni oludije fun ipo sẹnetọ ninu ẹgbẹ APC to fidirẹmi nipinlẹ Ọyọ.
Tinubu ni ko da, ọrẹ ni oun ati Ajimobi ati wi pe idi ti oun fi da si ọrọ APC ni Ọyọ ni lati ri wi pe ẹgbẹ naa ṣe daradara ninu idibo gomina to n bọ, kii ṣe wipe oun fẹ gba ipo lọwọ rẹ.
Atẹjade naa gbe ori yin fun Ajimobi.
'O ni o ṣe daradara ni Ọyọ ati wipe ohunkohun ti APC ba ri mu ni ipinlẹ naa, nitori Ajimọbi ni.'
O tun fi han wi pe nitori igbesẹ ti Tinubu gbe ni Ọyọ lo mu ki ọkan lara awọn oludije fun ipo gomina ni ipìnlẹ naa, Alao Akala pada si APC.
Tinubu ni iwe iroyin to gbe ofege iroyin naa nipa oun ati Ajimobi jade kan fẹ sọ ọmọ iya meji di ọta ara wọn ni.













