Russia 2018: Super eagles bẹ̀rẹ̀ ìgbáradì ní Austria

Ikọ Super Eagles ya fọto ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ kan

Oríṣun àwòrán, @thenff

Àkọlé àwòrán, Super Eagles gba Austria lọ lẹ́yìn ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ pẹ̀lú ikọ̀ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì lọ́jọ́ àbámẹ́ta

Ikọ agbabọọlu Super eagles ti gunlẹ si ilu Vienna lorilẹede Austria nibi ti wọn yoo tẹdo si ṣaaju idije ife ẹyẹ agbaye FIFA ti yoo waye lorilẹede Russia bẹrẹ lati ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa.

Fidio kan ti wọn fi si oju opo twitter ajọ elere bọọlu lorilẹede Naijiria, NFF lo fidi ọrọ yii mulẹ.

Ni ọjọ aiku lawọn agbabọọlu Super eagles fi ilu London silẹ lẹyin ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ ti wọn ti gba pẹlu ikọ ilẹ Gẹẹsi lọjọ abamẹta ni papa iṣire Wembley.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ikọ Super Eagles ti gunlẹ si Vienna. Wọn si ti kọri si ibudo ifiniwọsi Avita Resort Base camp nibiti wọn yoo ti maa gbaradi fun ọjọ diẹ."

Ni ọjọru ni ikọ Super eagles yoo tun fẹsẹwọnsẹ pẹlu ikọ Czech Republic lorilẹede Austria gẹgẹbii igbaradi ọlọrẹsọrẹ to kẹyin ninu igbaradi wọn fun idije FIFA ti ọdun yii.