You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Champions league: Real Madrid gba ife ẹ̀yẹ fún ìgbà kẹta ní tẹ̀lé ǹ tẹ̀lé
Ẹgbẹ agbabọọlu Real madrid ti gba ife ẹyẹ Champions league ti ọdun yii.
Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni wọn fi gbẹyẹ mọ liverpool lọwọ ni papa iṣire Kiev.
Kareem Bẹnzema lo kọkọ gba goolu wọle ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelaadọta ti aṣọle Liverpool ṣe aṣiṣe pẹlu bọọlu to fẹ ju si akọgbẹ rẹ.
Idamu ọkan bọ sagbo ikọ Liverpool nigbati ogunna gbongbo agbabọọlu wọn, Mohammed Salah ni lati jade kuro lori papa lẹyin ti o ti fi ejika rẹ ṣeṣe ninu itakangbọn pẹlu Sergio Ramos, Balogun ikọ Real Madrid.
Laipẹ rẹ naa ni agbabọọlu Real Madrid, Dani Carvajal pẹlu jade nitori oun pẹlu fara ṣeṣe.
Ko pẹ pupọ lẹyin eyi ti Mane, agbabọọlu Liverpool daa pada.
Amọṣa ọrọ yi pada nigbati Gareth Bale gba ikeji wọle fun Real Madrid ni iṣẹju kẹrinlelọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn iṣẹju mẹta lẹyin ti olukọni Real Madrid, Zinedine Zidane gbe e wọle.
Eyi ko dabi ẹni to Gareth Bale nitori isẹju kẹtalelọgọrin ifẹsẹwọnsẹ naa lo tun gba ayo miran wọle.
Gbogbo ija fitafita awọn agbọọlu Liverpool lo ja si pabo.