Ero awọn eniyan yato lori idajọ Ile ejo giga to sọ wipe awọn osisẹ ijoba le s'oselu
Laipẹ yii ni ile ẹjọ́ to ga ju lọ lorileede Naijiria (Supreme Court), gbe idajọ́ kalẹ̀ wipe awọn osisẹ́ ijọba le darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ oselu to ba wu wọn gẹ́gẹ́ bi i agbekalẹ̀ iwe ofin ọdun 1999.
Ofin eto idibo ti wọn gbe kalẹ̀ lọ́dun 2001 fi ofin de awọn osisẹ́ ijọba lati maa jẹ̀ẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ oselu kan-kan.
Idajọ́ naa ni wọ́n gbe kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bi ara alaye ile ẹjọ́ naa lori idajọ́ to ti kakọ́ se lọ́jọ́ kẹjọ, osu kọkanla ọdun 2002, ninu eyi to ti wọ́ igi lepupọ̀ ninu awọn ilana ti ajọ INEC gbe kalẹ̀ lori eto iforukọ silẹ̀ awọn ẹgbẹ́ oselu tuntun.
Lori idajọ́ tuntun yii, onimọ̀ nipa eto oselu orileede Naijiria, Ọ̀mọ̀we Gbade Ojo ni ohun to lewu pupọ̀ ni igbesẹ̀ ile ẹjọ́ naa jẹ̀.
Sugbọ́n lero ti ẹ̀, alaga ẹgbẹ́ awọn olukọ́ ni ipinlẹ̀ Ọ̀yọ́, Niyi Akano ni ohun to dara pupọ̀ ni igbesẹ̀ naa jẹ́ fun awọn osisẹ́ ijọba.









