Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ ògbóǹtagì oníṣòwò òògùn olóró méje

Awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti lilo ati tita oogun oloro ni Naijiria, NDLEA, ti mu eeyan meje to n ta oogun oloro ni ipinlẹ Kogi, Nasarawa ati Benue.

Lọwọ wọn ni wọn si ti ba oogun oloro Skunk ati Cocaine, ti ìwọ̀n rẹ tó kilogiraamu 843.

Àjọ NDLEA sọ pe ori omi laarin ipinlẹ Edo ati Kogi ni awọn eeyan naa, ti ọkùnrin kan, Augustine Emmanuel jẹ adari fún, gbe ọjà wọn gba, nitori ki ọwọ àwọn oṣiṣẹ ajọ naa ma tẹ wọn loju pópó.

Sugbọn, ọwọ pada tẹ wọn ni ọjọ kejila, oṣu Keje, ọdun 2021, lasiko ti awọn ẹṣọ alaabo da ọkọ Toyota Avalon ti wọn ko ẹrù oogun oloro si ninu gba ori omi lati Agenebode nipinlẹ Edo si Idah, nipinlẹ Kogi.

Ni Nasarawa, ibudo àwọn onisowo oogun oloro ni ọwọ ti tẹ àwọn mẹrin kan lasiko ti awọn oṣiṣẹ NDLEA kọlu wọn ni ọjọ kẹjọ, oṣu Keje. Ìwọ̀n igbó to to 356 kilogiraamu ati awọn oogun oloro míràn ni wọn gba lọwọ wọn.

Nibẹ si ni ọwọ ti tẹ onisowo oogun oloro to buru ju lọ ni ipinlẹ Nasarawa, Muhammed Umar 'Boogie'. Awọn ipinlẹ bi Kano, Plateau, Benue ati Abuja lo ma n ta ọjà rẹ si.

Awọn yooku ni ọwọ tẹ ni ipinlẹ Benue ni ọjọ kẹjọ, ọjọ kẹsàn-án, ati ọjọ kẹtala, oṣu Keje.

Ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Port Harcourt mú ẹ̀mí ènìyàn 5 lọ

Èyí wáyé lẹyin ọjọ́ kẹ́ta tí ìjọba ìpińlẹ̀ náà dẹwọ́ ìgbélé olóru mójú, eyí tó tí n wa nílẹ̀ láti bi oṣù méjì ṣẹyìn.

Ènìyàn márun un ló ti jẹ́ Ọlọ́run nípe níbi ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé l'oru ọjọ́ sátide lópòpóna NTA Mgbuoba ni Port Harcourt.

Ìjàmbá ọkọ̀ náà tó wáye nǹkan bi aago kan òru lẹ́yìn ọjọ́ kan ti ìjọba ìpińlẹ̀ Rivers dẹwọ́ ìgbélé òrumójú.

Ọlọ́pàá ti fìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ fún BBC lọ́jọ́ Sátidé.

Agbofinro ni: "Wọ́n ti gbé òkú àwọn máràrún náà lọ sí ilé ìgbókùú sí bí ìwádìí ṣe bẹ̀rẹ̀."

Nǹkan tí Nnamdi Omoni tó jẹ́ agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers só fún BBC.

Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sojú wọn ṣàlàyé pé mótò tí ó gbé àwọn ènìyàn márún un náà, ọkùnrin méjì àti àwọn obìnrin mẹ́ta lọ rọ́lu ọkọ̀ ńlá kan tó dúró lẹ́bà títì.

Ọkọ̀ tí ó máá n kó ìgbẹ́ ló wá lẹ́bà títì tí wọ́n sì kú lójú ẹsẹ̀ tí ìjàmbá náà ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹni náà ṣe sọ.

Ìròyìn sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásitì ni àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà, wọ́n sì ń bọ̀ láti ilé ijọ ní nigbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe, sùgbọ́n ọlọ́pàá kò fi ìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀.

Èyí wáyé lẹyin ọjọ́ mẹ́ta tí ìjọba ìpińlẹ̀ náà dẹwọ́ ìgbélé olóru mójú, eyí tó tí n wa nílẹ̀ láti bi oṣù méjì ṣẹyìn.

Àwọn olùgbé àdúgbò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ní ó ṣeeṣe kó jẹ́ pé wọ́n ń sarẹ àsápajúdé ni.

Ìṣẹ̀lẹ̀ náà dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ sílẹ̀ ni agbègbè náà.