EndSars Protest: A kò lọwọ́ sí ìwé ìpẹ̀jọ́ tó tako ìdásílẹ̀ ìgbìmò ìwádìí aṣemáṣe ikọ̀ SARS

Ileesẹ ọlọpaa lorileede Naijiria ti koro oju si iwe ipẹjọ kan to tako idasilẹ igbimọ iwadii lawọn ipinlẹ Naijiria eyi to n tọpinpin aṣemaṣe ìkọ ọlọpaa SARS.

Iwe ipẹjọ yi wa lati ẹka tó n mojuto ọrọ ileẹjo ileesẹ ọlọpaa kan naa.

Ninu atẹjade ti Frank Mba alukoro ọlọpaa fi sita lorukọ oga agba ọlọpaa Naijiria Muhamed Adamu, wọn ni iwadii yoo bẹrẹ lori bi iwe ipẹjọ yi ṣe waye.

Bakan naa lo sọ pe awọn ti kowe wa salaye tẹnu rẹ si ẹka igbẹjọ ọlọpaa t'awọn si ti ni ki adari ẹka naa wa sọ ohun to mọ nipa iwe ipẹjọ yi.

Adamu sọ pe ileesẹ ọlọpaa tunbọ tẹpẹlẹ mọ ifarajin rẹ lati ri wi pe wọn tu ìkọ SARS ka ni ibamu pẹlu ifẹ ara ilu.

Ni Ọjọbọ ni iroyin gbòde pe Ileesẹ ọlọpaa kọwe igbẹjọ lati tako idasilẹ awọn igbimọ iwadii eyi to n gbẹjọ lawọn ipinlẹ Naijiria kọọkan lori aṣemase ìkọ ọlọpaa SARS.

Nigba ti BBC yoo fi kan si ileesẹ ọlọpaa agbẹjọro wọn O.M Atoyebi sọ fun wa pe lootọ lawọn kọ ìwé ipẹjọ yi akọ awọn yoo wọgile niwaju ileẹjo pada lọjọ Ẹtì nitori bi ọrọ naa ṣe n lọ.

Nileẹjọ giga apapọ to wa ni Abuja ni wọn kọ iwe ipẹjọ yi sí lootọ ti wọn si sọ sinu rẹ pe ki ileẹjo wọgile awọn igbimọ wọn yi nitori wọn ko lasẹ lati jiroro lori ọrọ aṣemase SARS.

Bi a ko ba gbagbe awọn ọmọ ikọ SARS pade atako lati ọdọ araalu lori aiṣedede wọn lẹnu iṣẹ ati ifiyajẹni lati ọdọ wọn sí ara ilu.

Eyi mu ki awọn ọdọ beere ṣe iwọde fún iwọgile ikọ yi ati idasilẹ igbimọ iwadii ti yoo gbẹjọ lori aṣemase wọn.

Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko fún ẹbí àwọn ọlọ́pàá tó pàdánù ẹ̀mí lásìkò ìwọ́de EndSARS l'ẹ́bún owó 10 mílíọ̀nù

Ìjọba Ìpińlẹ̀ Eko tí fi orúkọ àwọn ọlọ́pàá tó kú lásìkò ìfẹ́hónúhàn #EndSars nípínlẹ̀ Eko.

Gómìnà ìpińlẹ̀ Eko Babajide Sanwol-Olu bákan náà tún fún àwọn ẹbí wọ́n ni míl''iọ̀nù mẹ́wàá náírà pẹ̀lú ìlérí pé àwọn ọmọ wan yóò lánfàní ìwé ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ títí dé fásitì.

Nínú oṣù kẹwàá ọdún 2020 ni àwọn ọ̀dọ́ yabo títì láti fẹ̀hónú hàn lórí bi àwọn ọlọ́p['a ṣe n hùwà ìkà sí àwọn ará ìlú tí wọ́n sì ń pè fún àtúnṣe. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dí èyí tó mú j]agídíjàgan dáni, ẹ̀mí àti dúkíà ọlọ́dan àti ti ìjọba ló lọ si pẹ̀lú.

Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko Babajide Sanwo-Olu ló fi sọ̀wédowó òun lé àwọn ẹbí olóògbé náà lọ́wọ́ lásìkò ìpàdé ètò ààbò kan lọ́jọ́bọ, bákan náà ló sèlérí pé, kò ni si ààyè fún ìwà ọdaràn.

Àwọn ọlọ́pàá tí ọ̀rọ̀ náà kan ni (ASP) Yaro Edward, Insìpẹ́kítọ̀ Ayodeji Erinfolami, Insìpẹ́kítọ̀ Aderibigbe Adegbenro, Insìpẹ́kítọ̀ Samsom Ehibor, sájẹ́ntì Bejide Abiodun àti Insìpẹ́kítọ̀ Igoche Cornelius.

O ní àwọn ọlọ́pàá wọ̀nyiì fi ẹ̀mi wọn rúbọ láti dáàbò bò ẹmi àti ǹkan ìní ará ìlú, ó ní owó náà wà fún ẹ̀san iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ti ṣe.

Ìjọba kò mẹ́nuba ọ̀rọ̀ àwọn ará ìlú tó kú tàbi farapa lásìkò ìfẹ́hónúhàn #EndSars, èyí tó mú wọ́n ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ̀ tó n gbẹ́jọ ìwà àìtọ́ tí àwọn ọlọ́pàá ti hù.

Ó ní " ìjọba yóo pèsè bílíọ̀nù mẹ́tàdílógójì ó lé díẹ̀ fún ètò ìlú àti ààbò nínú ètò ìṣúná ọdún 2021"

kọmíssọnà ọlapàá lásìkò ìpàdé náà sàlàyé pé àjọ ọlọpàaá kò jẹ́ ki ìwà ọ̀daran tó dín díẹ̀ ni ọ̀ọ̀dúnrún wáyé, nígbà ti wọ́n mú ọ̀daran tó le ni ẹgbẹ̀rún kan tí wọ́n sì pa mẹ́tàdílọ́gbọ̀n láàrín oṣù kẹwàá ọdún 2019 sí oṣù kẹsàán ọdún 2020.