You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Genevieve Nnaji: Ìbálòpọ̀ pẹlú ọ̀rẹ́kùnrin kọ́ ni ìfẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ kìí ṣe ìbálòpọ̀
Gbajugbaja oṣere ori itage Nollywood, Genevieve Nnaji ja gudugbẹ ọrọ lulẹ lori ọrọ ibalopọ ati ifẹ laarin ọkunrin ati obinrin.
Genevieve Nnaji gba awọn obinrin ni imọran ohun loju opo ikansiraẹni Facebook rẹ.
Genevieve woye pe "ẹni to ni Ibalopọ pẹlu rẹ le ma nifẹ rẹ, bakan naa ẹni to ni ifẹ rẹ denu le ma ni Ibalopọ pẹlu rẹ."
"Ẹyin obinrin ẹ ronu o, ọkunrin to korira rẹ le ba ọ sun," Genevieve kilọ.
O ni ofuutu fẹẹtẹ lasan ni erongba awọn obinrin kan to gbagbọ pe awọn le fi nini ibalopọ pẹlu ọkunrin mu un mọlẹ lati fẹ wọn gẹgẹ bi aya.
Genevieve ni "itanra ẹni jẹ ní kí obinrin maa ro pe oun le mu ki ọkunrin nifẹ oun nipa fífi ara rẹ silẹ fun Ibalopọ."
- Mi ò to iṣẹ́ Regina Daniels rárá kí n tó fẹ́ ẹ láàrin ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, mo sì tún le fẹ́ ìyàwó míì - Ned Nwoko
- Àwọn Ọba alayé ní Naijiria ṣàbẹ̀wò sí Ọba Eko, Gómìnà Eko àti Bola Tinubu Lẹyin ìwọ́de EndSARS
- Ohun tó yẹ kẹ́ẹ mọ nípà olùdíje mèjì tó lágbára nínú ìdìbò Ghana rèé
- Àyà mi já nígbà tí Ganduje rọ Sanusi lóyè Emir Kano tó fi Bayero síi, ṣùgbọ́n...- Ooni Ile Ife
O ni "ifẹ aiṣẹtan kii fi tipa mu obinrin lati ni Ibalopọ pẹlu rẹ."
Genevieve sọ pe "ọkunrin to ba ni ki o fi ìfẹ hàn s'oun nipa Ibalopọ n lo ẹ ni, yóò ja ẹ ju silẹ to ba ti ri ẹlomiran to gbadun Ibalopọ pẹlu rẹ ju ẹ lọ."
"Iwa omugọ ni ki obinrin sọ ara rẹ di ẹru ọkunrin fun Ibalopọ," Genevieve lo sọ bẹẹ.
O rọ àwọn obìnrin tí wọn ba ti n gbero lati fi Ibalopọ de ọkunrin mọlẹ pe ki wọn tun ero wọn pa, ki wọn si ṣe ipilẹ tuntun fun Irinajo ifẹ wọn.
Genevieve fikun ọrọ rẹ pe "ewu n bẹ loko longẹ fun igbeyawo ti ọkunrin ba fẹ obinrin nitori Ibalopọ."
"Gba lati fẹ ọkunrin to ba nifẹ rẹ denu, jẹ ki ọkunrin naa bu iyì fun ẹ, ki o si ṣetan lati lo gbogbo igbesi aye rẹ pẹlu rẹ," ọrọ ree lati ẹnu Genevieve.
- Ilé ìgbọ̀nsẹ̀ kan ṣoṣo ni aṣòfin mẹ́rin ń pín lò! Àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ Ogun pariwo sí Gómìnà wọn
- Ìdí tí mi ò fi lè parí ìjà pẹ̀lú Ààrẹ Ọ̀nà kakanfò, Gani Adams - Obasanjo
- Ṣé ẹ rántí àkọ́lé àwọn ìwé àkàgbádùn yìí?
- Àwọn Ọba alayé ní Naijiria ṣàbẹ̀wò sí Ọba Eko, Gómìnà Eko àti Bola Tinubu lẹyin ìwọ́de EndSARS