India: Ọmọ ọdun méje gbé bàbá rẹ̀ lọ àgọ́ ọlọ́pàá nítori ilé ìgbọ̀nsẹ̀

India

Oríṣun àwòrán, BBC Tamil

Àkọlé àwòrán, Hanifa Zaara ní bàbá òun parọ́ pé yóò kọ́ ilé ìgbọ̀nsẹ̀ tí òun bá se dáradára ní ilé ìwé, àmọ́ bàbá rẹ̀ kọ̀.

Lorilẹede India, ọmọ ọdun meje ti gbe baba rẹ lọ agọ ọlọpaa nitori pe ko kọ ile igbọnsẹ fun wọn ninu ile.

Hanifa Zaara ninu lẹta to kọ si ile isẹ ọlọpaa sọ wi pe baba oun rẹ oun jẹ nitori naa ki wọn fi panpẹ ọlọpaa gbe.

Zaara fi ẹsun kan baba rẹ wi pe o ni oun yoo ko ile igbọnse ti oun ba se daradara ni ile iwe, amọ baba rẹ kọ, botilẹ jẹ pe ọmọ naa ti n gbe gba oroke tipẹtipẹ.

Ọmọ ọdun meje naa fikun wi pe oun itiju lo jẹ fun oun laarin awọn ẹgbẹ oun ladugbo wi pe awọn ko ni ile igbọnsẹ ti eyi si jẹ ohun itiju laarin agboole fun idile oun.

Amọ, baba rẹ lasiko to n sọrọ ni agọ ọlọpa sọ wi pe ohun ti bẹrẹ si ni ko ile igbọnse naa, ati wi pe ohun ko le e pẹ kọ tan.

India

Oríṣun àwòrán, BBC Tamil

Àkọlé àwòrán, Baba rẹ ni ohun ti bẹrẹ si ni ko ile igbọnse naa, ati wi pe ohun ko le e pẹ kọ tan.

Ile isẹ ọlọpa ni ati bii ọjọ mẹwa ni ọmọ ọdun meje naa ko ti ba baba rẹ sọrọ ninu ile, ko to di wi pe ile isẹ ọlọpaa naa wa pẹtu si aawọ laarin baba ati ọmọ.

Iroyin ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu eniyan to n gbe lorilẹede India ni ko ni yara igbọn se si agbeegbe wọn.

Àkọlé fídíò, Òkè Ìdànrè: Òkè tó kéré jùlọ jẹ́ ẹsẹ̀ bàtà 3000