Irọ́ ni ọ́lọ́pàá npa nípa Dino - Olúránlọ́wọ́ fún Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, @dinomelaye
Oluranlọwọ pakati kan fun sẹnatọ to n soju ẹkun iwọ oorun Kogi, Dino Melaye sọ wipe irọ patapata ni awọn ọlọpaa n pa wipe sẹnatọ naa fo bọọlẹ ninu ọkọ ni olu ilu Naijiria, Abuja.
Oluranlọwọ naa nigba to n ba BBC sọrọ sọ wipe nise ni awọn ọlọpaa ti i bọọlẹ ninu ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn fi n gbe Melaye kuro ni Abuja losi Lọkọja lati lọ jẹjọ.
Amọ, awọn ọlọpaa sọ wipe awọn alatilẹyin Dino Melaye se ikọlu si ọkọ awọn ọlọpaa to n gbe Dino lọ, ti wọn si fayegba sẹnatọ naa lati fo bọọlẹ kuro ninu ọkọ awọn ọlọpaa.
Wọn ni awọn tọ ipasẹ rẹ lọ si ile- iwosan aladani kan nibi ti wọn ti lọ fi panpẹ ọba mu lẹlẹkeeji.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn alatilẹyin sẹnatọ naa sọwipe awọn ọlọpaa fi panpẹ ọba mu sẹnatọ naa nitori aawọ to wa laarin oun ati Gomina ipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ oselu APC kan naa.
Dino Melaye lo n soju ẹkun idibo iwọ oorun Kogi ni ile igbimọ asofin agba lorilẹede Naijiria.








