Leicester Cityvs Manchester United: Iheanacho lu Manchester United bí aṣọ òfi kúrò nínú ìdíje FA Cup

Yoruba lo maa n gbadura pe, iya aarọ tabi ti alẹ pe ki Eleduwa maa jẹ ki a jẹ ọkan kan ninu rẹ.

Amọ, ọrọ ko ri bẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United lẹyin ti ẹlẹsẹ ayo, ọmọ Naijiria, Kelechi Iheanacho fi iya aṣaalẹ jẹ wọn ninu idije FA Cup ilẹ Gẹẹsi.

Ami ayo meji ọtọtọ ni Iheanacho gba sawọn Man United ninu ifẹsẹwọnsẹ ti Leicester City ti digbaju ru Man U.

Youri Tielemans naa gbayo wọle Man U fun Leicester ti Man U si fidi rémi rẹmi pẹlu ami ayo mẹta sẹyọkan.

Mason Greenwood lo ja rabu rabu lati dayo kan pada fun Man U amọ ẹpa ẹpa ko boro mọ tori ọmi pọ ju ọka lọ.

Nibayii, Manchester United ti ja lulẹ ninu idije FA Cup nigba ti Leicester pegede fun abala to kangun si aṣekagba ninu idije naa.