You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
West Ham vs Chelsea: West Ham fi omi àbùkù wẹ Chelsea láwọlé sùn, Arsenal yìnbọn pa Norwich
Abuku oloronbo ni ẹgbẹ agbabọọlu West Ham United fi kan Chelsea lalẹ Ọjọru ninu idije Premier League.
Tomas Soucek lo kọkọ gba bọọlu sawọn fun West Ham nigba ti ifẹsẹwọnsẹ naa di iṣẹju mẹrinlelọgbọn, ṣugbọn ẹrọ VAR wọgile goolu ọhun.
O kudiẹ ki ipele akọkọ ere bọọlu naa pari ni Willian gba pẹnariti wọle fun Chelsea eyi to mu wọn ṣiwaju ninu ifẹsẹwọnsẹ naa.
- Cuppy kọ Arsenal sílẹ̀! Ọmọ Otedola bú sẹ́kún lẹ́yìn tí Brighton tún d'ẹrù ìyà lé Arsenal lórí
- Chelsea dun DJ Cuppy nínú lẹ̀yìn tí Arsenal gba omijé lójú rẹ̀
- Ògbóǹtarìgì agbábọ́ọ̀lù tẹníísìì Novak Djokovic ti lùgbàdì coronavirus
- A kò ní fara mọ́ fífi àkókò ṣòfò lórí ẹjọ́ Sotitobire - Ìjọba Ondo
- Àjọ NCDC kéde ènìyàn 790 tó tún ṣẹ̀ṣẹ̀ ní Coronavirus ní Nàìjíríà
- Àwọn èèkàn òṣèré Nollywood nìyí pẹ̀lú àmì ohùn èdè Yorùbá
- Ojú Shagbada Erigga rèé lẹ́yìn tó pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ l'Akinyele ní Ibadan
Amọ West Ham ko bẹṣu bẹgba nipele keji ere bọọlu ọhun, lẹyin iṣẹju mẹfa ti ipele keji gberasọ ni Michail Antonio dayo ti Chelsea gba wọle pada.
Gẹgẹ bi ẹ ti mọ pe Chelsea kii ṣe ẹran rirọ, Willian gba goolu mii wọle fun Chelsea, ni ere bọọlu ọhun ba di ọmi alayo mejimeji.
Ṣugbọn gudugbẹ ja nigba ti Andriy Yarmolenko gba goolu ẹlẹkẹta sawọn fun West Ham, nigba ti o ki iṣẹju kan pere ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari, lọrọ ba di wo mi n wo ọ.
Esi ifeṣẹwọnsẹ yii ti jẹ ki Manchester United sun mọ Chelsea ni kaṣan ọrun ninu ereje fun ati kopa ninu idije UEFA Champions League ni saa bọọlu to n bọ.
Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal gbarada lẹyin ti wọn run Norwich mọlẹ jegejege ni papa isẹre Emirates pẹlu ayo mẹrin ọtọtọ sodo.
Ẹlẹsẹ ayo, Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ ṣide goolu fun Arsenal ni bii iṣẹju mẹtalelọgbọn ti ere bọọlu naa gberasọ.
Lẹyin iṣẹju mẹrin ni agbabọọlu aringbungbun Granit Xhaka gba goolu keji sawọn fun awọn Gunners.
Aubameyang tun gba yo mii sawọn, ki Cedric Soares to fi ẹlẹẹkẹrin le.
Arsenal ti wa ni ipo kẹfa bayii lori tabili idije Premier League.
Koda gbajugbaja olorin, Florence Ifeoluwa Otedola ti ọpọ mọ si DJ Cuppy ti banujẹ pe nigba ti oun fi Arsenal silẹ darapọ mọ Man United ni Arsenal bẹrẹ si ni ṣe daadaa.
Niṣe lo n beere bo ya oun gan an lounṣe okunfa bi Arsenal ṣe n daku daji tẹlẹ.