You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Watford vs Chelsea: Chelsea sọjí lu Watford mọ́lé lẹ́yìn tí Man U fìyà jẹ wọ́n
Ooṣa ma jẹki ẹni to gọ o gbọn, ka le maa ri i tujẹ bi iṣu. Bayii lọrọrọ ri pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Chelsea nigba ti wọn koju Watford nile wọn.
Ẹ o ranti pe Manchester United lu Chelsea mọle laarin osẹ ninu idije Carabao Cup eleyi to mu Chelsea dero ile lati idije naa.
Amọ Watford lo fori kan iya ti Chelsea jẹ lọwọ Man U, ami ayo meji sẹyọkan ni Chelsea fi gbo ewuro soju Watford nile wọn.
- 'Mourinho ṣetán láti gbaṣẹ́ Arsenal, tó bá ṣí sílẹ̀'
- Ole mórí bọ́! Manchester United tún wẹ̀wù ìyà fún Chelsea lẹ́ẹ̀kan síi
- Mo bu ọlọ́pàá jẹ nígbà tó fẹ́ yín mi lọ́rùn ní Mushin- Àáfà
- Ẹni kan ti gbẹ́mìí mì; àwọn mẹ́rin ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn-LASEMA
- Èèdì rèé o! Olùkọ́ fẹgba lu akẹ́kọ́ọ̀bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá pa ní yàrá ìkàwé
- Buhari mórí lé ìlú London lẹ́yìn ìrìn-àjò lọ sí Saudi Arabia
Tamọtiye Tammy Abraham lo gbayo akọkọ sawọn Watford lẹyin iṣẹju marun un pere ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
Agbabọọlu ilẹ Amẹrika, Christian Pulisic lo gba goolu keji wọle fun Chelsea.
Amọ, Gerard Deulofeu dayo kan pada nigba to gba pẹnariti wọle Watford nigba ti ere bọọlu ku iṣẹju mẹwaa ti yoo fi pari.
Dákúdájí Manchester United tún ṣubú yakata nílé Bournemouth
Ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti di dakudaji bi ọkọ ẹ tii ẹ rọmi bayii, lẹyin ti Bournemouth fiya jẹ wọn lairotẹlẹ lọjọ Satide.
Lẹyin ti wọn lu Chelsea pẹlu ami kan sodo laarin osẹ ninu idije Carabao Cup, ọpọ lo ti ro pe Man U yoo fakọyọ nigba ti wọn ba koju Bournemouth.
Amọ, ami ayo kan sodo ni Bournemouth fi ṣagba wọn, Joshua King lo gbayo naa wọle nigba to ku diẹ ki ipele akọkọ ko pari.
Man U gbiyanju agbara wọn, amọ pabo ni gbogbo igbiyanju wọn jasi.