Sheffield United vs Arsenal: Evra ní Arsenal sì wà lọ́mọ ìkókó lẹ́yìn ọdún mẹ́wàá

Patrica Evra pẹlu awọn agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ko si iyatọ kankan ninu ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal lati bii ọdun mẹwaa sẹyin, bakan naa ni si wa.

Agbabọọlu ikọ Manchester United tẹlẹ ri, Patric Evra lo sọrọ yii lẹyin ti Sheffield United ṣina iya fun Arsenal lalẹ ọjọ Aje pẹlu ami ayo kan sodo ninu ifẹsẹwọnsẹ Premier League.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Arsenal padanu anfaani lati bọ si ipo kẹta ninu idije Premier League lẹyin ti wọn rẹmi papa iṣere Bramall Lane.

Evra ṣalaye pe ọmọ ikoko loun maa n pe wọn ni bii ọdun mẹwaa sẹyin nigba kugba tawọn ati Man U ba koju ara wọn.

Bakan naa lo sọ pe akọnimọọgba Unai Emery ko tii mu iyatọ kankan to ba Arsenal lati igba to ti gori aleefa lẹyin ti Arsene Wenger kuro.

Evra ni oun ko fi tabuku wọn, nigba ti oun sọ pe awọn agbabọọlu Arsenal n gbabọọlu bi ọmọ ọwọ, o ni otitọ loun n sọ.

Patrica Evra pẹlu awọn agbabọọlu Arsenal

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Evra to jẹ ọmọ orilẹede Faranse fikun ọrọ rẹ pe otittọ ni wi pe Arsenal dun un wo loju ti wọn ba n gbabọọlu, amọ o ni wọn ko jọ ikọ agbabọọlu to le maa fakọyọ ninu ere bọọlu.

O ni niṣe ninu oun maa n dun nigba kugba ti Man U ati Arsenal ba fẹ waako nitori oun mọ pe Man U yoo bori.

Adilemu fun Man U tẹlẹ ni Sheffield United gan an lo yẹ ko jawe olubori ninu ifẹsẹwọnsẹ alẹ ọjọ Aje nitori awọn lo fakọyọ julọ.