FIFAWWC: Super Falcons fi South Korea ṣ’ẹ̀bùn June 12 fún Nàìjíríà

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ikọ agbabọọlu obinrin Naijiria, Super Falcons naa ko gbẹyin bi orilẹede Naijiria ti bẹrẹ si sẹ ayajọ ọjọ ijọba awa arawa loni ọjọ kejila, oṣu kẹfa.

Super Falcons fẹyin South Korea gba lẹ pẹlu ami ayo meji sodo.

Kim Doyeon lo bun Naijiria ni goolu akọkọ lẹyin to gba bọọlu sinu awọn ile rẹ.

Ẹlẹsẹ ayo, Asisat Oshoala lo fi ọba le fun Naijiria pẹlu goolu keji fun Super Falcons.

Ọjọ ipinu fun Super Falcons

Oni la o mọ boya ẹgbẹ agbabọọlu obinrin orilẹede Naijiria, Super Falcons yoo le tẹsiwaju ninu idije ife ẹyẹ agbaye awọn obinrin to n lọ lọwọ lorilẹede Faranse.

Naijiria yoo koju ẹgbẹ agbabọọlu South Korea ninu ifẹsẹwọnsẹ keji wọn lẹyin ti wọn jẹ ajẹtun iya ami ayo mẹta sodo lọwọ Norway ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ ti wọn gba.

Amọ, akọnimọọgba Super Falcons, Thomas Dennerby sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria ṣe tan lati gbo ewuro soju South Korea lonii.

Dennerby ni pẹlu igboya lawọn agbabọọlu Naijiria yoo fi koju akẹgbẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe wọn fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ wọn pẹlu Norway.

O fikun ọrọ rẹ pe didun lọsan yoo so fun Naijiria ti Super Falcons ba le gba bọọlu bi wọn ṣe ṣe ninu abala keji ere bọọlu ti wọn gba pẹlu Norway.

Bakan naa, ẹlẹsẹ ayo, Asisat Oshoala sọ pe o ṣe ni laanu pe Super Falcons fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn, ṣugbọn o gbagbọ pe nnkan yoo yatọ ti wọn ba koju South Korea.

Ajọ to n ri si ere bọọlu ni Naijiria naa sọrọ loju opo Twitter wọn pe Super Falcons yoo jẹwọ orukọ wọn fun South Korea lọsan oni.

Ami ayo mẹrin sodo ni ẹgbẹ agbabọọlu South Korea fi jiya lọwọ France to n gbalejo idije ọhun ninu ifẹsẹwọnsẹ akọkọ wọn.

Ninu awọn ere bọọlu mii to wa lonii, France yoo waako pẹlu Norway to ṣeya fun Naijiria.

Bakan naa, Germany yoo maa gnena woju Spain ninu ere bọọlu miiran to yoo yeruku lala.