You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Super Falcons: 3-0 ni Norway fi ṣi'de ìyà fún Nàìjíríà
Orilẹede Norway ti si'de idije erebọọlu awọn abinrin ni agbaye, Women's World Cup pẹlu bi wọn se naa ikọ Super Falcons Naijiria pẹlu ami ayo mẹta si odo.
Guro Reiten ti ikọ Norway lo kọkọ gba bọọlu naa si inu awọn ni isẹju mẹtadinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ko to di wi pe Lisa-Marie Utland naa fi ọba le, to fi jẹ ami ayo meji si odo.
Osinachi Ohale ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria naa lo wa bọrọ jẹ patapata, ti o si gba bọọlu wọle si oju ile ara rẹ, eyi to mu ki ifẹsẹwọnsẹ naa pari si ami ayo mẹta si odo fun ikọ Norway.
Ikọ agbabọọlu Norway to gba Ife Ẹyẹ naa ni ọdun 1995 lo jawe olubori pẹlu bi ko se si gbajugbaja elere bọọlu wọn, Ada Hegerberg ni ifẹsẹwọnsẹ naa.