You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
France 2019: orílẹ̀-èdè Adulawọ mẹ́ta ló n lọ ṣojú Afirika
Orilẹ-ede France lo maa gbalejo awọn agbabọọlu obinrin ni gbogbo agbaye lọdun 2019.
Ọjọ keje, oṣu kẹfa ni idije ife ẹyẹ agbaye fawọn agbabọọlu obìnrin naa a bẹrẹ.
Naijiria, South Africa ati Cameroon ni orilẹ-ede mẹta to maa ṣoju ilẹ Adulawọ lapapọ.
Ikọ agbabọọlu mẹrinlelogun lo n ṣoju orilẹ-ede merinlelogun ti wọn yoo jọ dije gba ife ẹyẹ ti 2019 naa.
Ni Lyon ni France ni papa iṣerẹ ti wọn yoo ti gba aṣekagba idije naa lọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2019.
Papa iṣere mẹsan an ni ilu mẹsan an ọtọọtọ ni wọn a ti gba bọọlu naa.
Papa iṣere Parc Des Princes to jẹ ile fun Paris St-Gwermain ni wọn yoo ti gba idije ibẹrẹ ti wọn yoo fi ṣide ni France.
Papa iṣere Parc Olympique Lyonnais ti wọn tun n pe ni Groupama ni wọn yoo ti gba aṣekagba.
Papa iṣere yii ni wọn ti gba aṣekagba idije Europa League.
Oun naa ni wọn tun maa lo fun Summer Olympics to m bọ ni 2024.