You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pinnick: Àwọn ọ̀tá mi ló fẹ́ b'orúkọ mi jẹ́
Aarẹ ajọ elere bọọlu nilẹ wa, NFF, Amaju Pinnick ti ní kò sí òótọ́ kan ninu ìròyìn pé oun n koju ẹsun iwa ajẹbanu bayii, eyi ti owo rẹ to aimọye biliọnu naira.
Iroyin ti kọkọ sọ pé aarẹ Muhammadu Buhari ti pasẹ pe ki aarẹ NFF naa lọ foju winna igbẹjọ, lori awọn ẹsun ti wọn fi kan ọhun.
Bakan naa iroyin naa tun sọ pe ijọba apapọ ti fofin de Amaju Pinnick lati rinrin ajo lọ si oke okun lasiko yii titi ti igbẹjọ rẹ yoo fi buse.
Ni kete ti iroyin naa de afẹfẹ ni Pinnick ke gbajare lori Twitter pe ko si ootọ kan nibẹ.
Iwadi naa, gẹgẹ bi iroyin ṣe sọ, lo da lori owo ti ajọ elere bọọlu lagbaye FIFA, gbe fun ajọ elere bọọlu ilẹ wa, NFF, laarin ọdun 2014 si 2016.