You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Premier League: Everton dín'yà fún Chelsea pẹ̀lú àmì ayò 2-0
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1
Ẹgbẹ agbabọọlu Everton fẹyin Chelsea gbo lẹ ninu idije Premier League eleyi to jẹ ohun iyalẹnu.
Ami ayo meji ọtọtọ sodo ni Everton fi fagba han Chelsea ni papa isere Goodison Park nilẹ Gẹeṣi.
Agbabọọlu iwaju Richalison to jẹ omọ orilẹede Brazil lo gbayo akọkọ wọ le ni bi iṣẹju kan din laadọta.
Agbabọọlu aringbungbun Gylfi Sigurdsson lo fọba le fun Everton pẹlu ami ayo keji nigba ti ifẹsẹwọnsẹ ọhun de iṣẹju mejilelaadọrin.
Ipo kẹfa ni ikọ Chelsea wa bayii lori tabili idije Premier league ti Arsenal ati Manchester United si n siwaju wọn.