Aṣọ́lé Arsenal Petr Cech yoo fẹ̀yìntì nìdí bọ́ọ̀lù nipari sáà yí

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja aṣọle ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal Petr Cech ti kede pe oun yoo fẹyinti nidi ere bọọlu ni pari saa bọọlu yi.

Petr Cech ti o jẹ asọle fun ẹgbẹ Chelsea saaju ki o to lo dara pọ mọ́ Arsenal ni, asiko ti to lati kaṣẹ kikopa ninu ere bọọlu gẹgẹ bi aṣọle.

Lẹyin ti o lo ogun ọdun nidi ere bọọlu o fi ikede sita loju opo Twitter rẹ pe o ti to gẹ bayi.

Yatọ si Arsenal ati Chelsea, Cech tun ṣọle bọọlu fun Chmel Bisayn nibi ti o ti bẹrẹ ere bọọlu lọdun 1999, Sparta Prague lọdun 2001 ati Rennes .

Ni Rennes ni wọn ti ta lọ si Chelsea lọdun 2004 fun miliọnu meje pọun eleyi ti o jẹ owo to pọju lọ ti wọn san fun aṣọle lasiko naa ni Premier League.

Ọmọ orileede Czech Republic ni Petr, ti o si jẹ agbabọọlu ti o gba ifẹsẹwọnsẹ to pọju fun orileede rẹ ni igba mẹ́rìnlélọ́gọ́fà (124 Caps)

Awọn akẹgbẹ rẹ ati ikọ to gba bọọlu fun ti n ki ku orire:

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: