You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kipruto: Eléré orí pápá oníbàtá kàn tó gbégbá orókè
Bata meji ni ofin so pe eeyan gbọdọ fi bẹrẹ ere ori papa sugbọn kini ka ti se ti eeyan kan ba fi bata ẹsẹ kan pari idije ti o si tun gba ipo kini?
Oun ti gbajugbaja elere ori papa ọmọ Kenya kan ti orukọ rẹ n jẹ Conseslus kipruto se ree ni bi idije Diamond League Athletics Meeting to waye ni ilu Zurich laipẹ yii.
Ori ba a se e wi pe ko si ofin to de fifi bata kan pari idije.
Bata meji lo fi bẹrẹ ere ninu idije ẹlẹda pupọ oni mita 3000 (3000 meters steeplechase) fun awọn ọkunrin.
Nigba ti o de aarin kan ninu idije naa ni bata rẹ kan fo yọ sọnu ti eleyi si ṣe idiwọ diẹ fun un ninu idije naa.
Sugbọn Kipruto ko sọ ireti nu ti o si sapa titi ti o fi ja Soufiane El Bakkali ọmọ orileede Morocco silẹ lati gba ipo kini.
Awọn ọmọ orileede Kenya to fi mọ igbakeji William Ruto ti n kan sara si i pẹlu iwa akin yii.
Eyi kii se igba akọkọ ti oludije ere ori papa yoo padanu bata kan ti yoo si pada jawe olubori ninu idije naa.
Lọdun 2011, Dejen Gebremeskel to jẹ ọmọ orileede Ethiopia gba ami ẹyẹ ninu idije oni mita 3000m fun awọn ọkunrin ni Boston Indoor Games lẹyin ti bata rẹ fo yọ.
Mo Farah ọmọ ilẹ Gẹẹsi lo ṣe ipo keji.
Ni 2015, ọmọ Kenya Eliud Kipchoge pegede ninu idije Berlin Marathon toun ti bi itẹlẹ bata rẹ ti ṣe yọ bọ.