You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ẹ̀jẹ̀ ta sí Alex Ferguson l'ọ́pọlọ, wọ́n ṣ'isẹ́ abẹ fun
Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọlu Manchester nigba kan ri, Sir Alex Ferguson ni wọn ti ṣe iṣẹ abẹ pajawiri fun lati dóòlà ẹmi rẹ ni ọjọ Abamẹta nigba ti ẹ̀jẹ̀ ta si ni ọpọlọ.
Ẹgbẹ naa gbe atẹjade kan s'ita pe iṣẹ abẹ naa lọ daada, sugbọn Ferguson yoo wa ni ile iwosan fun igba diẹ
Akọnimọọgba naa ti o jẹ ẹni ọdun mẹrindinlọgọrin, gba ife ẹyẹ mejidinlogoji fun ẹgbẹ agbabọọlu na laarin odun mẹrindinlọgbọn to lo nibẹ.
Ferguson fẹyin ti ni oṣu karun, ọdun 2013.