Ọba Èkó; Ẹ dìbò fún Bùhárí, ó dára ju Ọbásanjọ́ lọ

Ọba Ilu Eko, Rilwan Akiolu ti gba awọn ọmọ Naijiria ni imọran lati fun Aarẹ Muhammadu Buhari laaye lati se aarẹ fun igba keji.

Akiolu to sọrọ nibi ayẹyẹ ẹlẹẹkẹtadinlogun ‘Lagos Housing Fair’ sọ wipe, fifun Aarẹ Buhari ni saa keji yoo mu igbugbooro ba ọrọ ajẹ orilẹede Naijiria.

Ọba Akiolu wipe, igba ati akoko Aarẹ Buhari dara ju ti igba Aarẹ tẹlẹri, Olusẹgun Ọbasanjọ lọ, to si fikun wipe, Aarẹ tẹlẹri, Goodluck Jonathan ko ba se daradara ti ko ba si awọn asebajẹ ti wọn jọ kọwọrin.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Lori ọrọ eto aabo lorilẹede Naijiria, Ọba Rilwan kesi Ijọba Apapọ lati se agbeyẹwo gbogbo awọn eto aabo to wa fun ẹkun kọọkan lorilẹede Naijiria.

Ti a ko ba gbagbe, Aarẹ Muhammadu Buhari ti sọ ero rẹ lati dije du ipo aarẹ lẹlẹẹkeji ninu idibo gbogboogbo tọdun 2019.