Ìdíje Champions league: Salah dá iná ayò sára Roma

Mohammed Salah ka ọwọ soke

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Àwọn èèyàn káàkiri àgbáyé ń pè fún gbígbé ádé agbábọ́ọ̀lù tó mọ̀ọ gbá jùlọ lágbáyé lé Salah lórí
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Mohammed Salah, agbábọ́ọ̀lù Liverpool tún jẹ́wọ́ ọmọ ọkọ ní àṣalẹ́ ọjọ́ ìṣẹ́gun, nígbà tí ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Liverpool na Roma pẹ̀lù àmì ayò márùn ún sí méjì.

Ifẹsẹwọnsẹ naa ni abala akọkọ ipele to kangun si aṣekagba ninu idije Champions league ilẹ Yuroopu, fun saa bọọlu afẹsẹgba ọdun 2017 si 2018.

Meji ninu ayo marun ti Liverpool gba wọ inu awọn Roma, lo wa lati ẹsẹ Salah.

Mohammed Salah pẹlu Firmino

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Iye goolu ti Salah ti wọnu awọn ni saa ere bọọlu yii ti di mẹtalelogoji

Ni bayii, iye goolu ti Salah ti wọnu awọn ni saa ere bọọlu yii ti di mẹtalelogoji.

Iṣẹju karundinlogoji ifẹsẹwọnsẹ naa ni Salah gba ayo akọkọ wọle ko to gba ikeji wọle ni iṣẹju karundinlaadọta.

Mohammed Salah fori balẹ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amọṣa ẹgbẹ agbabọọlu Roma ja fitafita lati da meji pada lati ẹsẹ First Edin Dzeko ati Diego Perotti

Sadio Mané gba ayo tirẹ wọle ni iṣẹju kẹrindinlọgọta, ki Firmino to gba meji wọle sii.

Amọṣa ẹgbẹ agbabọọlu Roma ja fitafita lati da meji pada lati ẹsẹ First Edin Dzeko ati Diego Perotti.

Mohammed Salah n waako pẹ̀lú agbablu Roma

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, 'Mo Salah ni agbabọọlu to fakọyọ julọ lagbaye bayii'

'Ẹ dée ládé e ọba bọ́ọ̀lù'

Bi o tilẹ jẹ wi pe, llati inu ikọ Roma ni Salah ti ko ẹru rẹ wa si Liverpool, ṣugbọn ko fi eyi ṣe, pẹlu bo ṣe tan bii irawọ ọsan, ti n ba agba lẹru ni gbogbo asiko ti ifẹsẹwọnsẹ naa fi waye.

Eleyi ti mu ki awọn eeyan kaakiri agbaye maa pe fun gbigbe ade ‘agbabọọlu to mọọ gba julọ lagbaye’ le Salah lori bayii.

'Mo Salah ni agbabọọlu to fakọyọ julọ lagbaye bayii'

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

'Mo Salah ti gbana jẹ'

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

'Mo Salah, Mo Salah, n da bi ẹdun'

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 3

'Mohammed Salah, ọlọwọ idan'

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 4

Skip X post, 5

End of X post, 5

'Wo ohun tawọ̀n ololufẹ̀ Liverpool ṣe lẹ̀yin ti Salah fakọ̀yọ̀ loni'

Skip X post, 6
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 6

'Ku iṣẹ Mohammed Salah'

Skip X post, 7
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 7

Chamberlain da àwọn olólùfẹ́ Liverpool, ilẹ̀Gẹ̀ẹ́sì sí hílàhílo

Alex Oxlade-Chamberlain ṣe fi ẹsẹ ṣeṣe ti wọn si gbee jade

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Alex Oxlade-Chamberlain ṣe fi ẹsẹ ṣeṣe ti wọn si gbee jade

Amọ ṣa o, nnkan kan ba ayọ aṣalẹ ọjọ iṣẹgun jẹ fun Liverpool.

Alex Oxlade-Chamberlain fi ẹsẹ rọ́

Ohun naa si ni pe, Alex Oxlade-Chamberlain fi ẹsẹ ṣeṣe, ti wọn si gbee jade.

Nibayii, ninu aibalẹ ọkan ni ọpọ awọn ololufẹ Liverpool wa bayii lori pe, ki ọrọ rẹ ma si di eyi ti ko ni lee gba bọọlu fun igba pipẹ, paapaa julọ bi idije ife ẹyẹ agbaye ṣe n bọ lọna.