You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Steven Pienaar fẹyinti nidi ere bọọlu
Agbabọọlu Everton ati Tottenham Hotspur nigba kan ri, Steven Pienaar ti kede ifẹyinti ninu ere bọọlu.
Pienaar to jẹ balogun ikọ agbabọọlu Bafana Bafana nigba kan ri kede ọrọ naa nirọlẹ ana loju opo twitter rẹ.
O ni: "Loni ni mo'n fẹyinti ninu ere bọọlu. Mo fẹ dupẹ lọwọ mama mi ati awọn ẹbi mi ati gbogbo ẹgbẹ agbabọọlu ti mo ti gba fun ati awọn alatilẹyin wọn, to fi mọ iwọ fun ara rẹ. Mi o le gbagbe rẹ. Mo dupẹ ifẹ ti ẹ fi han si mi"
"Ẹ maa bami kalọ lori ẹrọ ayelujara. Ikede kan nbọ lọna. Ẹyin lẹ o si kọkọ gbọ nipa rẹ''
Yatọ si Everton ati Tottenham, Pienaar tun gba bọọlu fun Sunderland ni Premier League.
Ṣaaju igba naa, o lo asiko diẹ pẹlu ẹgbẹ agbabọọlu Ajax Amsterdam ti Holand ati Borussia Dortmund lorilẹede Germany.