Winter Olympics 2018 - Ikẹtalelogun iru rẹ

Idije ere idaraya ti Winter Olympics 2018 ti ẹlẹẹketalelogun yoo bẹrẹ ni Olu-Ilu South-Korea, Pyeongchang lọjọ kẹsan si ọjọ karundinlogbon osu keji, ọdun 2018 pelu otutu to lamilaaka julọ ni itan orilẹede naa.

Lasiko ti wọn n gbaradi fun idije naa, orilẹede South ati North Korea fọwọsowọpọ fun igba akọkọ, ti wọn si parapọ yan awọn obinrin ti yoo soju wọn fun ere idaraya Hockey, ninu idije naa.

Iroyin fi lede wipe gbajugbaja elere idaraya to le ni ẹgbẹrun mẹta ni yoo kopa ninu Winter Olympics fun ayẹyẹ ami irawọ (Medal) to le lọgọrun ninu orisirisi ere idaraya marundinlogun.

Fun ẹkunrẹrẹ lẹsẹlẹsẹ lori bi ere idaraya Winter Olympics naa se n lọ, ẹ le kan si ẹka iroyin BBCTV, Redio, gbogbo ẹrọ ayelujara ti BBC ati ti oju opo BBC Sports.