EURO 2020: Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù England gbàgbọ́ pé àwọn lè gba ife ẹ̀yẹ EURO

Bi ẹgbẹ agbabọọlu England ṣe gbajugbaja to, wọn ko tii gba ife ẹyẹ EURO ri ninu itan wọn.

O ti pe ọdun marundinlọgọta ti England ti de ipele aṣekagba idije bọọlu afẹsẹgba to gbojigan kẹyin lẹyin ti wọn gba ife ẹyẹ agbaaye lọdun 1966.

Eyi túmọ si pe England ko tii de ipele aṣekagba idije EURO ri.

Akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu England, Gareth Southgate ko ṣai mọ eleyii, idi ree ti o fi kepe awọn agbabọọlu rẹ lati fakọyọ nigba ti wọn ba koju Denmark ninu ifẹsẹwọnsẹ to kangun sí aṣekagba alẹ Ọjọru.

Southgate ni lootọọ ni England ko tii de ipele aṣekagba idije EURO ri, ṣugbọn o ni awọn agbabọọlu oun ti ṣetan lati ṣe iwuri fun orilẹ-ede wọn.

O ni awọn agbabọọlu to n ṣoju England lọwọ yii le jẹ ikọ agbabọọlu akọkọ ti yoo gbe England wọ ipele aṣekagba idije EURO.

Southgate fikun ọrọ rẹ pe nkan idunnu ati iwuri lo jẹ pe gbogbo eeyan ilẹ Gẹẹsi lo wa lẹyin awọn.

"A ti wa ni igbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ pẹlu Denmark ti yoo waye ni papa iṣere Wembley.

Awọn agbabọọlu wa ti ni iriri ipele yii ri lẹyin ti a de ipele to kangun sí aṣekagba ninu idije ife ẹyẹ agbaaye ọdun 2018 ni Russia.

A mọ pe ko le rọrun pẹlu Denmark ṣugbọn ere bọọlu ti gbogbo eeyan yoo gbadun ni," Southgate lo sọ bẹẹ.

Akọnimọọgba ilẹ Gẹẹsi ni ko si ewu loko fún ikọ England afi giri aparo lasan.

Southgate ni Denmark lo le maa kọminu nitori awọn ni wọn ti gba ife naa lọdun 1992.