"Orí yọ mí lọ́wọ́ Erinmilókun àti Ọ̀ọ̀nì lásìkò tí mò ń pẹja àmọ́ ẹsẹ̀ mi lọ si"

    • Author, Mercy Juma
    • Role, BBC News
    • Reporting from, Lake Baringo

Láti ọmọ ọdún méjìlá ni Joseph Atuma ti ń pẹja nínú odò Lake Baringo tí ọọ̀nì àti erinmilókun wà nínú rẹ̀.

Pẹ̀lú bí àwọn ẹranko yìí ṣe wà nínú odò náà kò sí èyí tó ṣe ìkọlù si rí títí di inú oṣù Kẹsàn-án ọdún 2018 nígbà tí erinmilókun kan ṣe ìkọlù sí ọkọ̀ ojú omi rẹ̀ tó sì ya ẹsẹ̀ òsì rẹ̀.

Atuma, ẹni ọdún méjìlélógójì, ní inú igbó kan tó wà ní ẹ̀gbẹ́ odò náà ni erinmilókun náà sápamọ́, sí tí òun kò lérò pé ẹranko náà lè wá níbẹ̀, tó sì yọ sí òun ní òjijì.

"Ó ti eyín rẹ̀ bọ inú ọkọ̀ ojú omi onípákó tí mo wà, tó sì bù ú mọ́ ẹran ara mi.

Ẹran díẹ̀ ló kù lára egungun ẹsẹ̀ mi, láti ibi orunkún dé ibi kókósẹ̀ mi."

Odò Lake Baringo ní Rift Valley ní Kenya jẹ́ ọ̀kan lára àwọn odò tó tóbi ní orílẹ̀ èdè náà.

Atuma ní òun ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní dẹ odò padà báyìí lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí erinmilókun náà ṣe ìkọlù si.

Ó ṣàlàyé pé òun ti gbìyànjú láti ṣe àwọn iṣẹ́ mìíràn ṣùgbọ́n kò tó láti ṣe ìtọ́jú ẹbí òun nítorí iṣẹ́ apẹja ni ó jẹ́ òun lọ́wọ́.

Odò ń kún

Ó ní àwọn odò àti omi ti kún kọjá ju bó ṣe ń kún tẹ́lẹ̀ àti pé ìpìlẹ̀ ilé ìjọsìn kan tí odò ti bò mọ́lẹ̀ ni òun máa ń fi ọkọ̀ ojú omi òun tì sí báyìí.

Ó ní ọ̀pọ̀ ilé, ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn, òpópónà àti ẹ̀ka iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ẹja ní Kenya ni odò ti bò mọ́lẹ̀.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀ àwọn ìlú ló ti kó kúrò ní ibi tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀ nítorí ẹ̀kúnwọ́ omi.

Àwọn onímọ̀ àyíká ní odò náà ti kún wọ ìlọ́po méjì rẹ̀ láti bí ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn nítorí àpọ̀jù òjò àti àyípadà ojú ọjọ́.

Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ṣì ń lọ síbi odò náà nítorí wọ́n ń lò ó fún igbe ayé wọn.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn obìnrin ló máa ń lọ pọn omi, fọ aṣọ létí odò náà, tí àwọn míì sì máa ń mójútó àwọn ẹja tí àwọn apẹja bá pa wá fún wọn.

Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn erinmilókun, ọọ̀nì àti àwọn ẹranko inú tó lágbára náà wà nínú odò nítòsí.

Àwọn olùgbé agbègbè náà ní bí odò náà ṣe ń kún si ni àwọn ọ̀ọ̀nì àti àwọn erinmilókun ń pọ̀ si nínú odò náà tí wọ́n sì ti ń sún mọ́ ilé àwọn ènìyàn.

Èyí sì ti mú àlékún bá bí ẹ̀mí àwọn ènìyàn ṣe wà nínú ewu àti pé ọ̀ọ̀nì ti wọ́ àwọn ọmọdé sínú odò tí wọ́n kò sì rí wọn mọ́.

"Bí mo ṣe gbìyànjú láti fò, kí ń máa sálọ, ni Ọọ̀nì gbá ẹsẹ̀ mi mú, tó sì ń wọ́ mi lọ sínú odò"

Winnie Keben, ìyá ọlọ́mọ mẹ́fà, móríbọ́ lọ́wọ́ ìkọlù ọ̀ọ̀nì, ike ni wọ́n gbé sí ẹsẹ̀ rẹ̀ òsì báyìí láti lè máa fi rìn.

Keban ṣàlàyé pé omi ni òun lọ pọn ní odò lọ́jọ́ kan, bí òun ṣe pọn omi tán tí òun ń fò ẹsẹ̀ òun ni ọọ̀nì jáde sí òun.

"Bí mo ṣe gbìyànjú láti fò kí ń máa sálọ ni ọọ̀nì náà gbá ẹsẹ̀ mi mú tó sì ń wọ́ mi sínú odò."

"Mo bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo tí mo sì ń nawọ́ sókè kí àwọn ènìyàn lè rí mi, ọkọ mii tó wà nítòsí sáré wá láti wá gbà mí kalẹ̀."

"Bí àwa méjéèjì ṣe ń jà láti gbà mí lọ́wọ́ ọọ̀nì náà ni ẹnìkan tó wà níbẹ̀ mú àdá láti fi gé ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ọọ̀nì náà.

Ó ṣàlàyé pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gba ẹ̀mí òun là lọ́wọ́ ọọ̀nì ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ òun ti bá a lọ.

Oṣù mẹ́fà ni Keben lò ní ilé ìwòsàn àmọ́ nígbà tí ó ma fi dé omi ti gba gbogbo ilé rẹ̀. Ibi tó jìnà sí odò ló ń gbé báyìí, kò sí lọ sí etí odò náà láti ìgbà náà.

Ó fi kun pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ti yí padà lágbègbè náà nítorí kìí sí omíyalé agbára ya ṣọ́ọ̀bù ní agbègbè náà ṣùgbọ́n lásìkò yìí tí wọ́n bá dáko wọn kìí rí èrè rẹ̀ kó nítorí omíyalé agbára ya ṣọ́ọ̀bù.

"Ẹ̀rù máa ń bà mí pé tí mo bá lọ sí etí odò náà pé ọ̀ọ̀nì ṣì lè ṣe ìkọlù sí mi."

Àwọn olùgbé agbègbè náà mẹ́rìndínláàdọ́rin ló ti pe ìjọba lẹ́jọ́ pé ìjọba kò mójútó ìjàm̀bá tí àyípadà ojú ọjọ́ ń kóbá agbègbè náà.

Àpérò ilẹ̀ Adúláwọ̀ lórí àyípadà ojú ọjọ́

Ẹjọ́ tí àwọn ènìyàn yìí pè ló ń wáyé lásìkò tí ìjọba orílẹ̀ èdè náà àti àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Adúláwọ̀ (AU) ṣe ń ṣèpàdé ní Nairobi, olú ìlú Kenya, níbi tí Ààrẹ Kenya, Willam Ruto lọ pẹ̀lú ọkọ̀ tó ń lo iná mọ̀nàmọ́ná.

Gẹ́gẹ́ bí àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé (UN) ṣe sọ, ìdá méjì sí mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún àwọn nǹkan tó ń fa àyípadà ojú ọjọ́ ló ń wá láti ilé Adúláwọ̀ àmọ́ àwọn ni àkóbá rẹ̀ ń bá fínra jùlọ.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbi àpérò náà, Ruto ní ilẹ̀ Adúláwọ̀ yóò nílò ọ̀pọ̀lọpọ̀ tírílíọ̀nù dọ́là láti fi ṣe àtúnṣe àwọn àkóbá tí àyípadà ojú ọjọ́ ń kóbá ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Orílẹ̀ èdè United Arab Emirates (UAE) ti ṣèlérí láti pèsè ìdókoòwò tí iye rẹ̀ tó $4.5bn lórí àyípadà ojú ọjọ́ sí ilẹ̀ Adúláwọ̀.

Bákan náà ni ìjọba UK náà jẹ́jẹ̀ẹ́ láti pèsè àwọn àkànṣe iṣẹ́ tó tó mílíọ̀nù mọ́kànlélọ́gọ́ta dọ́là sí ẹkùn Adúláwọ̀ láti kojú àwọn àkóbá àyípadà ojú ọjọ́.

Lára rẹ̀ ni pípèsè mílíọ̀nù mẹ́tàlélógójì dọ́là láti fi ṣe àkànṣe iṣẹ́ láti fi ran àwọn obìnrin àti àwọn àgbẹ̀ tí àyípadà ojú ọjọ́ ń ṣe àkóbá fún lọ́wọ́.

Àwọn tó pe ìjọba lẹ́jọ́ náà ní ìjọba Kenya kò mójútó àyípadà ojú ọjọ́ tó ń fa òṣì àti àìsàn sí àwọn nítorí bí odò náà ṣe ń kún àkúnjù ní gbogbo ìgbà.

Wọ́n ní kí ìjọba fún àwọn ní owó àti àwọn ẹbí mìíràn tí tí wọ́n ti pàdánù ilẹ̀, oko àti àwọn nǹkan mìíràn lórí bí odò náà ṣe ń kún.

Ìjọba kò ì tíì fèsì ẹjọ́ tí wọ́n pè.

Fún Atuma, odò náà ṣì ni ohun tó fi ń wá oúnjẹ oòjọ́ rẹ̀ àmọ́ gbogbo ìgbà ni ẹ̀rù ọọ̀nì àti erinmilókun máa ń bà á.

Ó ní omi kún dókè ní àsìkò yìí ní èyí tó túmọ̀ sí pé àwọn ẹranko yìí máa ń wà sókè níbi tí omi kò pọ̀ sí, tí wọ́n sì ń sún mọ́ ènìyàn.