You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìdájọ́ lásán la gbà, a kò gba ìdájọ́ òdodo èyí tó lòdì sí ìfẹ́ aráàlú - PDP/Labour
Ní alẹ́ ọjọ́rú, ọjọ́ Kẹfà, oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ni ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ tó wáyé lọ́jọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Kejì ọdún 2023 gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀.
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò náà ní Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò náà lóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí INEC ṣe kéde.
Atiku Abubakar ti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Peter Obi ti ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party àti ẹgbẹ́ òṣèlú APM ló ń pe ìjáwé olúborí Tinubu lẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò.
Wọ́n ní àwọn ní àwọn jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò tó gbé Tinubu wọlé àti pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ kùdìẹ̀kudiẹ ló wáyé lásìkò ìbò náà.
Adájọ́ Haruna Simon Tsammani tó ṣáájú ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún náà nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní àwọn olùpẹjọ́ kọ̀ láti fi ìdí ẹjọ́ wọn múlẹ̀ tó sì dá ẹjọ́ náà nù.
Ó fi kun pé àwọn olùpẹjọ́ kò sọ ní pàtó àwọn ibi tí àìṣe déédéé ti wáyé lásìkò ìbò ààrẹ ọ̀hún.
Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Labour Party àti iléeṣẹ́ Ààrẹ ti sọ ìhà tí wọ́n kọ sí ìdájọ́ náà.
Ìdájọ́ lásán la gbà, a kò gba ìdájọ́ òdodo - PDP
Ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ti ní àwọn ti ṣàgbéyẹ̀wò ìdájọ́ tí ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ awuyewuye ìbò ààrẹ gbé kalẹ̀ lọ́jọ́rú àti pé àwọn kò gba ìdájọ́ ìdájọ́ náà wọlé.
Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Debo Ologunagba fi síta ní ìdájọ́ náà kò lọ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ẹ̀rí tí àwọn kó síwájú ìgbìmọ̀ náà.
Ologunagba ní ìdájọ́ ọ̀hún kò lọ ní ìbámu pẹ̀lú ìwé òfin Nàìjíríà àti pé kò fi ìdájọ́ òdodo lélẹ̀ lórí ohun tí ẹjọ́ náà dá lé lórí.
Ó ṣàlàyé pé gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń máa ń tẹ̀lé òfin, àwọn yóò jókòó pẹ̀lú àwọn agbejọ́rò àwọn láti ṣe àtúngbéyẹ̀wò ìdájọ́ náà dáradára kí àwọn fi mọ ìgbésẹ̀ tó kàn tí àwọn máa gbé.
Bákan náà ló rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti wà ní ìṣọ̀kan, kí wọ́n sì fi ọkàn balẹ̀ nítorí gbogbo ọ̀nà ni àwọn máa fi ri dájú pé ìjọba àwaarawa kò dojú délẹ̀ ní Nàìjíríà àti pé ìfẹ́ àwọn ènìyàn lórí ìbò ààrẹ wá sí ìmúṣẹ.
Ìdájọ́ Kotẹmilọrun lòdì sí ìfẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà - Labour Party
Ọ̀rọ̀ kò yàtọ̀ lọ́dọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party bí àwọn náà ṣe bu ẹnu àtẹ́ lu ìdájọ́ tó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Tinubu ló jáwé olúborí ìbò Ààrẹ.
Agbenusọ Labour Party, Obiora Ifoh nínú àtẹ̀jáde kan ní ìdájọ́ náà kò wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àti pé kìí ṣe ìfẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà.
Ó ní àwọn ọmọ Nàìjíríà ló rí gbogbo èrú tó wáyé lásìkò ìbò ààrẹ ọ̀hún àti pé gbogbo àgbáyé ni wọ́n ti bu ẹnu àtẹ́ lu ètò ìdìbò náà.
Ó wòye pé ìjọba àwaarawa ni ìdájọ́ náà yóò ṣe àkóbá fún àmọ́ àwọn kò ní kó àárẹ̀ ọkàn àyàfi tí ìfẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà bá wá sí ìmúṣẹ.
Ó kan sáárá sí àwọn agbejọ́rò wọn fún bí wọ́n ṣe dúró bí ọmọ akin, tí wọ́n fi ojú ìbàjẹ́ tó ti gbokùn ní Nàìjíríà hàn.
Ó fi kun pé àwọn máa fi ìgbésẹ̀ tó bá kàn nínú ẹgbẹ́ léde lẹ́yìn àwọn bá ti ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn agbejọ́rò àwọn àti tí àwọn bá ti gba àkọ́ọ́lẹ̀ ìdájọ́ náà dání, tí àwọn ti ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ fínnífínní.
Ó fi kun ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kí àwọn ọmọ Nàìjíríà má mi kàn nítorí Nàìjíríà tuntun ń bọ̀ wá sí ìmúṣẹ.
Ẹ jẹ́ ká jọ pawọ́pọ̀ tún Nàìjíríà ṣe -Tinubu
Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ohun tó kọjú sí ènìyàn kan, ẹ̀yìn ló kọ sí ẹlòmíràn.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kan sáárá sí ìdájọ́ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò tó sì jẹ́jẹ̀ẹ́ láti túnbọ̀ sí Nàìjíríà tọkàntọkàn.
Tinubu sọ àrídájú rẹ̀ pé òun yóò túnbọ̀ máa ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ àti gbé àwọn kalẹ̀ tí yóò mú ìlọsíwájú àti ìdàgbàsókè bá Nàìjíríà láì fi ẹ̀yà, ẹ̀sìn tàbí ẹgbẹ́ òṣèlú kankan ṣe.
Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ Tinubu, Ajuri Ngelale fi síta ní òun yin àwọn Adájọ́ márùn-ún tí wọ́n gbé ìdájọ́ náà kalẹ̀ lákin fún bí wọ́n ṣe ri pé wọn kò dojú ìdájọ́ délẹ̀.
Ó ní èyí fi hàn pé ẹ̀ka ètò ìdájọ́ Nàìjíríà ń gbòòrò si àti pé ìṣèjọba àwaarawa ní Nàìjíríà ń túnbọ̀ ń dúró ire si lásìkò tí ìṣèjọba àwaarawa ń dójú délẹ̀ ní àwọn orílẹ̀ èdè kan ní ilẹ̀ Adúláwọ̀.
Tinubu fi kun pé òun ní ìgbàgbọ́ pé àwọn olùdíje àtàwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ló ní ẹ̀tọ́ lábẹ́ òfin láti kópa níbi ètò ìdìbò àti láti lọ sí ilé ẹjọ́ bí èsì ìdìbò kò bá tẹ́wọn lọ́rùn.
Ó rọ àwọn tí wọ́n jọ díje náà láti jẹ ìwúrí fún àwọn alátìlẹyìn wọn nípa gbígbárùkù tí ìṣèjọba tó wà lóde kí ìgbé ayé le rọrùn fún àwọn ọmọ Nàìjíríà.