Wo kókó ìgbésẹ̀ 13 tí Tinubu gbé láàrin ọgọ́rùn-ùn ọjọ́ tó di ààrẹ

Ni ọjọ Kọkandinlọgbọn osu Karun ọdun 2023 ni aarẹ ana , Muhammadu Buhari, gbe akoso orilẹede yii kalẹ fun ijọba alagbada miran.

Ẹni to lewaju ijọba alagbada tuntun naa ni Bola Ahmed Tinubu to soju ẹgbẹ oselu APC lasiko idibo aarẹ to kọja.

Ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kẹjọ osu Kẹsan ọdun 2023 si ni o pe ọgọrun ọjọ ti ijọba tuntun naa gori aleefa.

Bi awada, bi ere, ọgọrun ọjọ ti kọja lọ lati igba ti Bola Tinubu bẹrẹ ijọba rẹ gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

Laarin ọgọrun ọjọ naa, ọpọ ojo lo ti rọ, ti ilẹ si ti fi mu lẹka isejọba orilẹede yii eyi to nipa rere tabi idakeji rẹ lara awọn ọmọ Naijiria.

"Oriṣirisi ipenija lo ti koju Naijiria laarin ọgọrun ọjọ akọkọ ti Tinubu di aarẹ"

Yoruba ni bi egungun baa mọọ jo, ori a maa ya atọkun.

Eyi gan an lo mu ki minisita eto iroyin ati ilanilọye, Mallam Mohammed Idris ka awọn aṣeyọri aarẹ Tinubu lẹsẹẹsẹ.

BBC Yoruba ti wa se akojọpọ awọn koko ohun ti ijọba tuntun naa, labẹ idari aarẹ Bola Ahmed Tinubu ti gbe se lati igba to ti wa lori aleefa.

Mallam Mohammed Idris ni lootọọ, oriṣirisi ipenija ni o ti koju Naijiria laarin ọgọrun ọjọ akọkọ ti Tinubu di aarẹ, ṣugbọn aarẹ ko dawọ iṣẹ duro lati ri pe ilọsiwaju ba orilẹede yii.

Koko mẹtala igbesẹ ti Tinubu gbe laarin ọgrun ọjọ to di aarẹ

  • Aṣeyọri akọkọ Tinubu gẹgẹ bi minisita eto iroyin ṣe sọ ni igbesẹ rẹ lati yọ owo iranwọ ori epo eyi to n ṣakoba fun ọrọ aje Naijiria kuro. O ṣalaye wi pe owo iranwọ ori epo yii lo jẹ ki Naijiria wọ obitibiti gbese fun ọpọ ọdun sẹyin
  • Ijọba Tinubu tun ṣeto iranlọwọ fawọn araalu ki igbesẹ yiyọ owo iranwọ kuro ma le ni ipa to le lara wọn
  • Ohun miiran ti Tinubu ṣe ni lati da oniruuru ọjọ pasipaarọ owo dọla si naira di ọkan ṣoṣo. Mallam Mohammed ni awọn igbesẹ yii ko ṣai mu inira wa, amọ, Aarẹ Tinubu ti n fi dawọn eeyan loju pe igba ọtun si n bọ
  • Ijọba ti n jiroro pẹlu ẹgbẹ awọn oṣisẹ lati ṣe afikun owo oṣu wọn, bakan naa ni ijọba Tinubu gbe owo nla fawọn gomina kaakiri ipinlẹ mẹrẹẹrindinlogoji lati ṣe iranwọ fawọn eeyan ti ebi n pa nipinlẹ wọn
  • Laarin ọgọrun ọdun akọkọ rẹ lọfiisi, Tinubu pin ajilẹ lọpọ yanturu fawọn agbẹ
  • Ijọba apapọ pin ounjẹ fun ogunlọgọ papaa julọ awọn ọmọ Naijiria ti ko ri ọwọ họri
  • Bakan naa ni iṣẹ n lọ lori ati pin ọkọ ero ẹgbẹrun mọkanla ti yoo maa gbe awọn eeyan ni ẹdinwo kaakiri orilẹede Naijiria
  • Aarẹ Tinubu tun di alaga ajọ ECOWAS to n ri si ọrọ awọn orilẹede iwọ oorun ilẹ Afirika, eleyii si ti mu iyi ba orukọ orilẹede Naijiria sii lagbaaye
  • Ijọba Tinubu tun ti gbe igbesẹ ti yoo pese ọgunlọgọ miliọnu iṣẹ fawọn ọmọ Naijiria
  • Aarẹ Tinubu ti ṣiṣẹ takun takun lati ri pe alaafia jọba lagbo oṣelu Naijiria nitori lai si alaafia ilọsiwaju ko le waye
  • Ijọba Tinubu tun ti ṣiṣẹ lati pana iwa ẹlẹya mẹya lawọn awọn ọmọ Naijiria, o si ti ri pe ibaṣepọ to dan mọran ti wa laarin awọn ọmọ Naijiria
  • Lati le ri pe iṣọkan wa ni Naijiria, Aarẹ Tinubu ko ṣegbe lẹyin ẹya kankan nipa iyansipo awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ to fi mọ awọn olori ẹṣọ ọmogun.