Ẹ fọkànbalẹ̀, Naira sí ǹ bọ̀ wá níyì ju Dọ́là lọ - Adeboye

Pasitọ agba fun Ijọ Redeemed Christian Church of God, Pasitọ Enoch Adeboye ti sọ asọtẹlẹ pe owo naira orilẹede yii yoo ni okiki ju owo ilẹ Amẹrika, Dọla lọ.

Adeboye sọ gbolohun yii lọjọ Aiku lasiko to n ṣe iwasu nibi eto idupẹ kan to waye ni ẹka ijọ rẹ to wa ni agbegbe Ebute Metta niluu Eko.

Lasiko to n sọrọ, Adeboye salaye pe nigba kan owo naira niyi ju owo dọla, to si lagbara pupọ lawujọ.

O wa ṣe adura pe laipẹ, iyanu yoo sẹlẹ si owo naira naa, ti yoo si ba ẹgbẹ pe.

“Nigba kan wa ti owo naira niyi ju dọla lọ, ẹ ma foya, asiko ọhun tun pada pọ.

“Boya ti eyi ba waye, ẹ gbagbọ pe onisẹ iyanu ni Oluwa .”

Lọwọlọwọ bayii, owo dọla kan ni eeyan le sẹ si owo naira N915 si N918, ti owo naira si n rakoro lẹgbẹ awọn owo ilẹ okere yooku.

Ipenija yii lo n ṣe ọpọlọpọ akoba fun okowo ati igbayegbadun awọn eeyan, paapa lẹyin ti ijọba yọ owo iranwọ epo bẹntirolu.”