You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Pásítọ̀ ṣẹ̀èṣì fi àbẹ́là àti lọ́fíńdà dáná sun ọmọ ìjọ lásìkò àdúrà ìtúsílẹ̀, ó dèrò àgọ́ ọlọ́pàá!
Pasitọ kan, Taiwo Odebiyi, ti dero agọ ọlọpaa nipinlẹ Ogun lẹyin to ṣeṣi dana sun obinrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Sukura Owodunni, lasiko to n ṣe itusilẹ fun un.
Ile ijọsin Cherubim and Seraphim Maberu, to wa Offin, ni Shagamu ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Ileeṣẹ iroyin Punch jabọ pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2023 yii ni iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti obirin naa lọ ba pasitọ ọhun fun adura.
Iroyin ni pasitọ Odebiyi sọ fun obinrin ọhun pe ko ra ororo oloorun didun, ẹyin ibilẹ ati abẹla fun itusilẹ ti yoo ṣe fun.
A gbọ pe asiko ti adura naa n lọ lọwọ ni pasito da ororo oloorun didun ọhun l e Sukura lori to si tan ina si abẹla ọwọ rẹ, eyii to mu ki ina sọ.
Ni kete to ṣa ina si abẹla naa tan ni ina sọ lara Sukura, ti ina ọhun si jo ni aya, ejika ati ẹsẹ.
Awọn oṣojumikoro ni ko pẹ lẹyin iṣẹlẹ naa ni wọn fi ọrọ ọhun lọ ọlọpaa, ti awọn agbofinro si fi ṣikun ofin mu pastọ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Omolola Odutola, ti fidi iroyin naa mulẹ.
Odutola sọ pe awọn ti gbe iwadii dide lori ẹkunrẹrẹ ohun to ṣẹlẹ, awọn yoo si tu iṣu iṣẹlẹ naa de isale ikoko.
O ni “Wọn fi obinrin naa silẹ lati ṣe itọju ara rẹ… o si ti wa nile iwosan bayii.”
“Awọn agbofinro wa ti mu afurasi, o a si tare ẹjọ naa lọ si ẹka State CID lẹyin ti a ba ti pari iwadii wa tan.”