You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akẹ́kọ̀ọ́ kú lásìkò tó ń pidán níbi ayẹyẹ ilé ẹ̀kọ́ rẹ̀
Akẹ́kọ̀ọ́ ipele kẹta kan ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Akenten Appiah-Menka University of Skills Training and Entrepreneurial Development (AAMUSTED) ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lásìkò tí wọ́n ń ṣeré ní ilé ẹ̀kọ́ náà.
Iná mú Prosper Owusu lára lásìkò tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ kan ní ilé ẹ̀kọ́ náà ní ọjọ́ Karùndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹjọ ọdún 2023.
Fídíò kan tó gbòde ṣàfihàn bí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé.
Fídíò ọ̀hún fi hàn bí àwọn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wọ aṣọ pupa ṣe pọ̀ níbi ayẹyẹ náà tí wọ́n sì ń kọrin.
Bákan náà ló ṣàfihàn bí Prosper ṣe mú kòbókò dání pẹ̀lú ọtí ṣìnáàpù ní ìbẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ náà.
Bí ilẹ̀ ṣe ń ṣú, tó sì fẹ́ pidán náà ló rìn kọjá nínú iná tí aṣọ rẹ̀ sì múná.
Bí ara rẹ̀ ṣe bẹ̀rẹ̀ sí ní jóná nìyẹn tó sì ń pariwo.
Àwọn èrò ìwòran kàn ń wò ó bí ó ṣe ń pariwo pé ara òun ń jóná ni.
Lẹ́yìn ètò náà ni wọ́n gbé Prosper lọ sí ilé ìwòsàn olùkọ́ni Komfo Anokye.
Láti ìgbà náà sì ni àwọn dókítà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní tọ́jú Prosper.
Ilé ẹ̀kọ́ ní òun ń ṣèwádìí ayẹyẹ tó mú ìjàmbá iná wáyé
Fídíò mìíràn tún ṣàfihàn bí wọ́n ṣe fi aṣọ wé ní gbogbo ara.
Ó ní òun ń gbọ́ lásìkò tí òun ń pidán náà tí wọ́n ń pariwo pé kí àwọn ènìyàn sá.
Prosper ní ìgbà náà ni òun wo ẹ̀yìn tí òun sì ri pé aṣọ òun ti múná.
Pẹ̀lú gbogbo ìgbìyànjú àwọn dókítà, Prosper jáde láyé lọ́jọ́ kìíní oṣù Kẹsàn-án ọdún 2023 ní ilé ìwòsàn náà.
Àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà ní Prosper jẹ́ ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Opoku Ware (ll) tí wọ́n ń ṣe ayẹyẹ lásìkò tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Ilé ẹ̀kọ́ náà ní àwọn gbé lọ sí ilé ìwòsàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.
Àtẹ̀jáde láti ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún ní àwọn ń ṣèwádìí ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe kí ìjàmbá iná ọ̀hún tó ṣẹlẹ̀.
Wọ́n pàrọwà sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti jìnà sí àwọn ayẹyẹ tó le mú ewu lọ́wọ́.
Bákan náà ni wọ́n bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó di olóògbé náà kẹ́dùn.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tí ń fa awuyewuye lórí ayélujára.
Bí àwọn kan ṣe ń bá Prosper kẹ́dùn ni àwọn mìíràn ń sọ wí pé kí ló sun dé ìdí eré líle náà.