You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọlọ́pàá fí èsì ìwádìí ikú ọmọ Davido, Ifeanyi Adeleke síta...
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko ti fi idi rẹ mulẹ pe esi abajade iwadii iku ọmọ Davido ti jade sita.
Gẹgẹ bi ọrọ agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, iwadii safihan pe ọmọ naa mu omi yo ninu adagun omi ‘’Swimming pool’’ ni.
Bakan naa lo fikun un pe wọn ti gbe awọn afurasi meji ninu iṣẹlẹ naa lọ si ẹka to n risi ọrọ ọdaran, SCID ti ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko.
Alẹ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye.
Isẹlẹ iku ọmọde yii lo dun awọn eeyan de ọkan, paapaa ọna to ba ku.
Ọpọ awọn osere tiata, akọrin, awọn oloselu atawọn agbaagba lawujọ si ti n ransẹ ibanikẹdun si ẹbi Adeleke.
Ṣé lóòtọ́ọ́ ni Ọlọ́pàá mú Eniola Badmus lórí ikú ọmọ Davido?
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn pé Eniola Badmus wà ní àhámọ́
Gbajugbaja osere tiata to tun jẹ ọrẹ timọtimọ fun olori takasufe, ni iroyin ti gbe kiri pe o ti wa pẹlu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko.
Idi ti iroyin naa ni wọn fi gbe Eniola ni pe ko le wa wi tẹnu rẹ lori iku Ifeanyi Adeleke tii se gbajumọ ọmọ olorin takansufe, Davido
Ifeanyi lo ku sinu omi odo iluwẹ to wa ninu ile wọn lọjọ Aje, ti ọlọpaa Eko si ko Nani ọmọ naa ati kuku inu ile ọhun si ahamọ.
Iroyin naa ni alagbatọ fun Ifeanyi Adeleke to di oloogbe, lo sọ fun ileeṣẹ ọlọpaa pe Eniola lo pe oun lori ẹrọ ibaraẹnisọrọ, ti oun fi fi ọmọ silẹ lati lọ gbe ipe naa.
Bakan naa ni wọn ni Eniola Badmus lo jẹ ẹni akọkọ to kọkọ gbe iroyin lori iku ọmọ Davido si ori ayelujara, kete ti iṣẹlẹ naa waye.
Igbesẹ Eniola Badmus ni o ti da ọpọlọpọ awuyewuye silẹ lori ayelujara ti ọpọ si n bu ẹnu atẹlu bi o ṣe kọkọ jẹ ẹni akọkọ to gbe iroyin naa sita
Eniola Badmus ko si ni ahamọ wa, ofege ni iroyin pe ọlọpaa ti mu u.
Iroyin to n lọ kiri yii lo mu ki ileeṣẹ BBC kan si ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko lati fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin to ba wa sọrọ ni iroyin ofege lasan ni iroyin, ti ko si ohun to jọ bẹ rara.
Hundeyin ni iwadi si n lọ lọwọ lori iku ọmọ Davido, eyiun Ifeanyi Adeleke.
“Mo n sọ fun yin pe ko si nkan to jọ mọ bẹ rara.
“Iwadi wa si daleri awọn meji ti a kọkọ mu, ti wọn si wa ni ọdọ lọwọlọwọ bayii.”
Ki lo ti sẹlẹ saaju lori iku Ifeanyi Adeleke?
Alẹ ọjọ Aje ni iroyin gbalẹ kan pe Ifeanyichukwu tii se ọmọkunrin kan soso ti gbajumọ akọrin takansufe, Davido bi ti jade laye.
Ọpọ eeyan naa ni iroyin ọhun n se ni kami kami kami, ti wọn ko si fẹ gba ikede iku ọmọ naa gbọ.
Amọ nigba to di aarọ ọjọ keji ni agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin fidi isẹlẹ naa mulẹ fun awọn akọroyin pe lootọ ni Ifeanyi ti jade laye.
O ni ọmọ naa lo ko sinu omi ti wọn fi n luwẹ to wa ni ile Davido lasiko ti baba ati iya rẹ ko fi si ninu ile.
O ni o si pẹ ki wọn to sakiyesi pe ọmọ naa ti ku sinu omi, ti ọlọpaa si ti ko awọn osisẹ mẹjọ to n sisẹ ninu ile Davido fun ifọrọwanilẹnuwo.
Amọ nigba to di aarọ ọjọru, ileesẹ ọlọpaa Eko ni oun ti fi mẹfa ninu awọn osisẹ naa silẹ, ti meji to ku si ni ẹjọ lati jẹ lori iku ọmọ ọdun mẹta naa.
Bakan naa lo ni o seese ki wọn se ayẹwo oku ọmọ naa lati tubọ mọ ọna to ba lọ si ọrun aibaamọ ejo le lọwọ ninu.
Isẹlẹ iku ọmọde yii lo dun awọn eeyan de ọkan, paapaa ọna to ba ku.
Ọpọ awọn osere tiata, akọrin, awọn oloselu atawọn agbaagba lawujọ si ti n ransẹ ibanikẹdun si ẹbi Adeleke.